Bàbá kan fipá bá ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́rin lòpọ̀ ní Pọtá

ojiji ọmọbinrin kan
Àkọlé àwòrán,

Ifipábanilòpọ̀ máa ń fa ẹ̀rù, ìbànújẹ́ àti ìrònú ni

Ilé ẹjọ́ Magistrate kan tó wà ní ìlú Port Harcourt ní ìpínlẹ̀ Rivers ti ju ọkùnrin kan sẹ́wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàń án pé ó ń fipá bá àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin mẹ́rin lajọṣepọ̀.

Michael Akpan Isaiah, to jẹ aṣọ́gbà ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ipá bá àwọn ọmọ nàá tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọdún méjì, méje, mọ́kàńlá àti mẹ́tàdínlógún, ló ń kojú ẹ̀sùn mẹ́ta tó ní i ṣe pẹ̀lú ìfipá-báni-lòpọ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí agbẹjọ́rò kankan tó ṣojú rẹ̀ ní ilé ẹjọ́, ó faramọ́ èrò ilé ẹjọ́, ṣùgbọ́n ó ní ''èṣù ló ti òun'' láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítori pé "òun n bẹ lábẹ́ ìdarí àwọn ẹ̀mí burukú ni."

Adájọ́ ilé ẹjọ́ nàá, Onídàjọ́ Zinna O. Alikor ní, nkan èèwọ̀, ìṣẹ́ ibi, tó fi mọ́ ìwà ìkà ni ohun tí ọkùnrin nàá ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Abikẹ Dabiri: Iṣẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ Naptin àti àwọn aṣọ́bodè Nàìjíríà

Ìdájọ́

Adájọ́ ní, ilé ẹjọ nàá kò ní agbára láti gbọ́ ẹjọ nàá, ṣùgbọ́n ó pa á láṣẹ pé kí wọ́n gbé ìwé ẹjọ́ nàá lọ síwájú Olùdarí iléesẹ́ tó wà fún ìgbẹ́jọ́ fún ìmọ̀ràn tó yẹ.

Ẹ̀wẹ̀, ó ní kí wọ́n fi ọ̀kùnrin nàá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nàá títí di ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ yóò maa tẹ̀síwájú.

Nínú ẹ̀rí tó jẹ́ nílé ẹjọ́, aṣojú ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò obìnrin ní Nàìjíríà, (FIDA), Fortune Ada Ndah, sọ fún ilé ẹjọ pé ó ti lé ní ọdún mẹ́ta tí olùjẹ́jọ́ ọ̀hún tí n fi tipá-tipá ṣe kòtọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Àti pé, àwọn ní èsì àyẹ̀wò ilé ìwòsàn tó fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Ndah ní, níṣe ni Alikor maa ń na àwọn ọmọbìnrin nàá bíi bàrà lásìkò tó bá ti fẹ́ bá wọn lòpọ̀.

Ṣùgbọn, àṣírí tú lásìkò tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ka a mọ́ ìdí ìwà burúkú náà. Lẹyìn èyí ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ ọhun tó iléèṣẹ́ tó n ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Rivers létí.

Ẹ̀wẹ̀, ó di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ nàá ru ìyá àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí pé kò súnmọ́ àwọn ọmọbìnrin nàá bó ṣe tọ́, bíbẹ̀kọ̀ọ́, ì bá ti mọ̀ pé irú nkan bẹ̀ n wáyé.

Ṣùgbọ́n, ìyá àwọn ọmọ náà ní ''òun fí ẹjọ́ ọkọ òun sun àwọn ẹbí rẹ̀ nígbà tí òun ṣe àkíyésí àrà tó n fi àwọn ọmọbìnrin náà dà, àmọ́ tí wọn kò gbé ìgbésẹ̀ kankan. Àti pé, níṣe ni ọkùnrin nàá n dún kookò mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá takòó.