Ṣé ó ṣeéṣe kí ìtàn tún ara rẹ̀ sọ nínú ìdìbò gómìnà l'Ekiti?

Eleka ati Fayẹmi
Àkọlé àwòrán,

Ẹlẹka àti Fayẹmi ni yoo ṣoju ẹgbẹ PDP ati APC ninu eto idibo gomina to m bọ ni Ekiti

Ta ni yóò kó lọ sílé ìjọba ni Adó Ekiti?

Ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keje ni ètò ìdìbò sípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ekiti yọò wáyé.

Oríṣiríṣi ìgbáradì ló sì ti n wáyé nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó n kópa, pàápàá ni All Progressives Congress, (APC) àti Peoples Democratic Party, (PDP).

Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí ni ẹgbẹ́ APC ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́tàdínlọ́gọ́rin láti polongo fún olùdíje ẹgbẹ́ nàá, Kayọde Fayẹmi. Àwọn gómìnà mẹ́rìndínlógún ni yóò darí ikọ̀ ìpolongo náà.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí fídíò kan ṣe àfihàn àwọn ọ̀dọ́ kan tó n ba pátákó ìpolongo ìbò Fayẹmi jẹ́.

Bákan náà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti lọwọlọwọ, Ayọdele Fayoṣe, naa léwájú ètò àdúrà kan, níbi tó ti sọ pé ''kò sí bí igbákejì òun yóò ṣe kùnà nínú ètò ìdìbò náà''.

Ìròyìn kan tilẹ̀ tún sọ pé Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ pé ''òun mọ̀ pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti kò ní ṣe àṣìse láti díbó yan PDP lẹ́ẹ̀kan si i.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ má-ni-gbàgbé nípa ìdìbò gómìnà Ekiti ní 2014

Bi ọmọ kò bá bá ìtàn, ó di dandan kó bá àrọ́bá.

Nínú ètò ìdìbò gómìnà tó wáyé ní ìpínlẹ̀ nàá l'óṣù Kẹfà, 2014, oríṣiríṣi awuyewuye ló wáyé ṣaajú àti lẹ́yìn ètò ìdìbò nàá.

Àwọn òṣiṣẹ́ elétò ààbò dá àwọn gómìnà kan láti inú ẹgbẹ́ All Progressives Congress pada. Wọn kọ̀ láti jẹ ki wọn wọ ìpínlẹ̀ Ekiti lọ́jọ́ tí ètò ìdìbò naa ku ọjọ́ méjì.

Èròngbà àwọn gómìnà ọhun, tó fi bá àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC, ni láti darapọ̀ mọ́ àṣekágbá ipolongo ìbó fún aṣojú ẹgbẹ́ rẹ, tó tún jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti lásìkò idibo náà, Kayọde Fayẹmi.

Lara àwọn gómìnà ọ̀hún ni Rotimi Amaechi, tó ti di mínísítà fún ètò ìrìnnà báyìí, àti Adams Oshiomole, tó jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Edo lásìkò náà.

Ẹgbẹ́ APC, ní abajade ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ní, dídá tí àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọ̀n dúró.

Ati pe igbesẹ yii kò ṣẹ̀yìn àṣẹ tó wá láti òkè ki àwọn má lè ri ọwọ mu ni.

Ni idakeji ẹ̀wẹ̀, awọn tí PDP ní ọ̀nà láti mú kí ìdìbò náà lọ láì sí rúdurùdu kankan ni ijọba PDP to wa lori aleefa lasiko yii ṣe gbe igbesẹ naa.

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ PDP àti APC tí n lérí pé ọwọ́ àwọn ni ipò gómìnà yóò bọ́ sí l'Ekiti

Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn ètò ìdìbò náà ni ọmọ iléesẹ́ ológun kan, Ọ̀gágun Sagir Koli, fi fọ́nrán kan síta, èyí 'tó ṣe àfihàn ohùn àwọn èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, nínú èyí tí a ti rí mínísítà fún ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Jelili Adesiyan, Musiliu Ọbanikoro, Iyiola Omisore, Ayọdele Fayose, ti oun náà jẹ́ olùdíje lasiko yii, tó tun wa padà jáwé olúborí.

Nínú fọ́nrán ọ̀hún ni wọ́n ti n jíròrò lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbà 'ṣe màgòmágó' ìbò nà, ṣùgbọ́n tí ẹgbẹ́ PDP ní kò rí bẹ́ẹ̀.

Jelili Adeṣiyan ní òótọ́ ni fọ́nrán ọhun, àmọ́ kíì ṣe ọ̀rọ̀ àti dabarú ìbó rara. Ó ní níṣe ni Fayose n fẹ̀sùn kan Ọ̀gágun Aliyu Momoh, tó tukọ̀ ìdìbò náà pé ó gba owó ẹ̀yìn lọ́wọ́ Kayode Fayẹmi àtẹgbẹ́ APC.

Bákan nàá, ni Fayose ní àdọ́gbọ́nsí ni fọ́nràn náà.

Taa ni ìjọba àpapọ̀ yóò tìlẹ́yìn báyìí?

Lẹ́yìn tí ètò ìdìbò nàá wáyé ni akọ̀wé gbogbogbò fún PDP lásìkò ọhun, Temitope Aluko, lásìkò ìfọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò tó ṣe lórí ẹ̀rọ́ amóhùnmáwòrán TVC, ní ''ẹgbẹ́ PDP lo agbára ìjọba apàpọ̀ láti yẹ̀yẹ́ àwọn olórí ẹgbẹ́ APC, táwọn sì tún fi àwọn kan sí àhámọ́."

Ṣùgbọ́n ní bàyíì tó jẹ́ pé ẹgbẹ́ APC ló wà n dari Naijiria nipò ààrẹ, ta ni ìjọba apàpọ̀ yóò sẹ àtìlẹyìn fún nínu ètò ìdìbò gómìnà tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Ekiti ní oṣù Keje 2018?

Njẹ́ ó ṣeéṣe kí APC náà lo 'agbára òkè láti yẹ̀yẹ́ tàbí fi ìyà jẹ' àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP lásìkò ètò ìdìbò náà?

Ipa wo ni Musiliu Ọbanikoro tó jẹ́ ògúnná gbòǹgbò nínú ìgbìmọ̀ tó ṣe ètò bí PDP sẹ 'ṣe mọ̀dàrú ìbò tó gbé Fayoṣe wọlé ní 2014', (gẹ́gẹ́ bí fọ́nrán tó jáde ọ̀hún ṣe sọ), yóò kò nínú ìdìbò tó n bọ̀ pẹ̀lú bí ó ṣe tún wà nínú igbimọ ìpolongo APC báyìí?