SDP: A kò tíì fún Omiṣore ní àṣíà olùdíje gómínà

Idanimọ ẹgbẹ oṣelu SDP
Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ oṣelu SDP ní gbogbo ọ̀nà tó yẹ kí Omiṣore rìn gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ ló ti rìn

Ẹgbẹ oṣelu SDP ti ṣalaye wi pe, lootọ ni igbakeji gomina nigbakan nipinlẹ Ọṣun, Ọtunba Iyiọla Omiṣore ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.

Ẹgbẹ oṣelu SDP ni, yatọ si oloye Omiṣore, gbaragada ni ilẹkun ẹgbẹ oṣelu naa ṣi silẹ fun awọn oloṣelu to ba fẹ darapọ.

Alaga ẹgbẹ oselu SDP nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Ishọla Ademọla, ni alaye naa ṣe pataki nitori ọrọ kan to gba ori opo iroyin lorilẹede Naijiria kan laipẹ yii , nipa ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa kan to ni Omiṣore kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu SDP.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ọmọ ẹgbẹ oṣelu SDP ni Omisoore, gbogbo igbesẹ to yẹ ki ẹnikẹni to ba fẹ darapọ mọ ẹgbẹ wa gbe, naa lo ti gbe.

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ oṣelu SDP ko tii fa aṣia oludije fun ipo gomina Ọṣun le Omiṣore, tabi ẹnikẹni lọwọ

O fẹ dupo gomina labẹ ẹgbẹ SDP gẹgẹbii awọn oludije miran. Aaye wa fun ẹnikẹni to ba darapọ mọ wa lati ṣe bẹẹ nitori ojo ni wa, a ko ba ẹnikẹni ṣọta."

Amọ ṣa, awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa yanana rẹ pe, ẹgbẹ oṣelu SDP ko tii fa aṣia oludije fun ipo gomina Ọṣun le Omiṣore, tabi ẹnikẹni lọwọ ati pe, awọn ọmọ ẹgbẹ ni yoo si yan ẹni ti wọn ba fẹ.