UN gbé mílíọ́nù méjì dọ́là kalẹ̀ fún ìtọ́jú onígbáméjì

Awọn obinrin n dana

Oríṣun àwòrán, @UN_Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Àjàkálẹ̀ ààrùn onígbáméjì ti di kálé n káko láwọn ìpínlẹ̀ bíi Borno, Yobe àti Adamawa

Ajọ iṣọkan agbaye ti ya miliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika sọtọ lati ṣe agbatẹru igbesẹ lati koju arun onigbameji to bẹ silẹ lagbegbe ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Ko din ni aadọta eeyan ti arun onigbameji yii ti ran lọ sọrun lati ibẹrẹ ajakalẹ aarun ọhun ni opin oṣu kẹta.

Owo ti ajọ iṣọkan agbaye gbe kalẹ naa yoo wa fun ipese omi to mọ gaara fun awọn eeyan to ju miliọnu kan ati ẹgbẹta lọ, ko si tun ṣeto ayika to peye fun awọn agbegbe ti ọrọ kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìjọ Àgùdà: Kò dára ká máa ké gbàmí-gbàmí kiri lójoojúmọ́

Gẹgẹ bii ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, CDC ṣe sọ, ko din ni ẹgbẹrun mẹta iṣẹlẹ arun onigbameji to ti waye, ti o si tun ti gba ẹmi awọn eeyan kaakiri orilẹede Naijiria, paapaa lawọn ipinlẹ kan lẹkun ila oorun ariwa bii Borno, Adamawa ati Yobe.

Alamojuto eto iranwọ labẹ ajọ iṣọkan agbaye lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe, ajakalẹ arun onigbameji lee pa ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan, paapaa julọ awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn n gbe lawọn iagbegbe bii ibudo awọn ti wahala Boko Haram le kuro nile.

Oríṣun àwòrán, @UN_Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Awọn omi ati ounjẹ ti ko mọ pẹlu ayika ti o kun fun ẹgbin kun ara awọn ohun ti wọn ni o n ṣokunfa aarun onigbameji

Amọ ṣa, ajọ iṣọkan agbaye ti ni, wọn ṣi nilo alekun owo, paapaa lasiko ojo, nigba ti aisan to rọ mọ omi yoo pọ.

Awọn omi ati ounjẹ ti ko mọ, pẹlu ayika ti o kun fun ẹgbin kun ara awọn ohun ti wọn ni o n ṣokunfa ọwọja aarun onigbameji.