Kòkòrò ajokorun da ìpòruru sí ọkan àwọn àgbẹ̀ Nàìjíríà

Kòkòrò ajokorun
Àkọlé àwòrán,

Kòkòrò ajokorun le sọ àgbẹ̀ di ẹdun arinle toba ya wọ oko.

''Mo ti ṣe àbẹwò sí àwọn oko kan láwọn ìletò kaaakiri ile kaarọ ojiire ti ohun ti a sì rí ní bẹ kọnilominu nitori ijamba ti kòkòrò ajokorun n ṣe. Bi a ko ba wa wọrọkọ fi ṣada ni kíá, o lè ṣe àkóbá fún ìpèsè oúnjẹ lọdun yìí''.

Ọrọ ree láti ẹnu ọmọwe Olugbenga Egbetokun nigba ti o n ba ìkọ BBC Yoruba sọrọ lórí ìpeníjà kòkòrò ajokorun to n dá ìpòruru sí ọkan àwọn àgbẹ̀ Nàìjíríà.

Ọmowé Olugbenga wà lára àwọn tó n ṣíṣe nípa ọgbin àgbàdo ní ilé iṣẹ iwadi ijinlẹ IAR and T to wa ni agbegbe Àpáta Ibadan.

Àwọn onimọ nípa isẹ agbẹ sapejuwe kokoro ajokorun to sẹ̀sẹ̀ sẹ́ wọlu gẹ́gẹ́ bi Arun Ebola fun àwọn agbẹ́.

O ni, ọdún 2016 láwọn kọkọ kojú ìpeníjà kòkòrò ajekorun náà.

''Ogbẹle to sẹlẹ lọdun yẹn lo ran itankalẹ awọn kòkòrò naa lowo''

Nípasẹ ṣíṣe àkóso ètò nnkan ọgbin, Olugbenga sọ wi pé awọn kòkòrò wọnyi ti n jẹ ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó yẹ ki àgbẹ̀ kò lérè.

Ẹ gbọ ohun to sọ nipa kòkòrò náà.

"Ebola tiwá ni kòkòrò ajokorun"

Tope Amujo n ṣíṣe pẹlú àwọn àgbẹ̀ ní ìpínlè Kwara Osun ati Oyo.

O ni àwọn àgbẹ̀ náà kò rí eré tó yẹ kí wọn rí latari ìpeníjà kòkòrò ajokorun yìí.

''Ọpọ nínú wọn ló yá owó ìrànwọ́ láti ọdọ àwọn àjọ àlàjẹ́sẹku ṣugbọn tí wọn kò lè rí sàn padà mọ nítorí pé kòkòrò yii tí ṣé àkóbá fún nnkan oko won.''

Amujo ní ìgbìyànjú láti ṣe idanilẹkọ fún àwọn àgbẹ̀ n lọ káàkiri lórí kòkòrò ajokorun yii ṣùgbọ́n tí kòkòrò náà bá tí wọ inú okò tán, afi kí èèyàn máà gbà ádùrá.

Ati okere loloju jinjin ti''n mekun sun

Àwọn onímọ̀ nípa ètò nnkan ọgbin ṣàlàyé pé òun tí àwọn àgbẹ̀ lè ṣe láti dẹ́kun ìpeníjà kòkòrò yii kò jù wí pé kí wọn tètè yà owó kikoju rẹ bọ inu ìṣirò.

Ọmowé Olugbenga ni ''bi èèyàn bá ní pé òun yóò dúró títí tí kòkòrò náà bá wọ inú okò tán kí òun tó ná owó sí ìtànkálẹ̀ rẹ̀, ẹpa kò ní boro mọ.''

''Ki o tó di pé kòkòrò náà wọ inú okò, a gbọ́dọ̀ tí rà àwọn òògùn apá kòkòrò kì a sì máà fin wọn lóòrèkóòrè sí nnkan ọ̀gbìn wà. Bi a bá ṣè eléyìí tán, kí a gbàdúrà pé kí kòkòrò náà má yà inú okò wà''.