Ebola: ìjọba Gẹ̀ẹ́sì fún DR Congo lówó láti fi gbógunti i

Maapu DR Congo
Àkọlé àwòrán,

DR Congo ń ja ogun Ebola lójú méjèèjì lásìkò yìí

Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́si fẹ́ pèsè miliọnu marun un pọun fún gbígbógunti Ebola ni Democratic Republic of Congo

Wọn kede pé Ebola tún ṣẹyọ ni Bikoro tó jẹ ileto ni ariwa Kinshasa to jẹ olu ilu DR Congo ni èyí to ti ń mu ẹ̀rù ba àwọn ènìyàn kaakiri ilẹ̀ Adulawọ bayii.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Ebola to lágbára sẹyìn:

Ikú ènìyàn 11,308 lorilẹ-ede Guinea, Liberia, Sierra Leone, laarin ọdun 2014 si ọdun 2016

Ikú ènìyàn 280 lorilẹ-ede DR Congo, l'ọdun 1976

Ikú ènìyàn 254 lorilẹ-ede DR Congo, l'ọdun 1995

Ikú ènìyàn 224 lorilẹ-ede Uganda, l'ọdun 2000

Ikú ènìyàn 187 lorilẹ-ede DR Congo, l'ọdun 2007

(Orisun: WHO)

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bayii, Ebola ti pa eniyan mẹtadinlọgbọn ni DR Congo ni eyi to dẹ tun ń tàn kalẹ lati ileto lọ si àwọn ilu nla bii Mbandaka, ti wọn ti ri iṣẹlẹ Ebola tuntun lọjọ kẹtadinlogun oṣu karun un.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ebola ti di ohun ti gbogbo àgbáyé ń mójútó báyìí

Iranlọwọ ilẹ United Kingdom yii yoo jẹ ki iṣẹ tubọ rọrun fún àjọ WHO to n mojuto ìlera agbaye lati ri si ìtànkálẹ̀ Ebola.

Ajọ WHO n mojuto pe ki Ebola má tankalẹ sii, wọn ń ṣayẹwo fun iṣẹlẹ Ebola tuntun, wọn tun n pese iranwọ lori ipolongo abẹrẹ ajẹsara Ebola to n lọ lọwọ.

Ipolongo imọtoto lori fifọ ọwọ́ nigba gbogbo ati idanilékọọ lori ṣiṣe ayẹwo Ebola n lọ ni DR Congo sii.

Awọn ajọ aranilọwọ loriṣiriṣii náà ti wa ni Congo bayii ti wón n pese iranlọwọ fún wọn.