Jonathan ṣí afárá ọkọ̀ tuntun ní Adó Èkìtì

Aarẹ ana Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọrọ aarẹ Jonathan ko ṣẹyin gbogbo pọpọṣinṣin idibo gomina nipinlẹ Ekiti

Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan lo sọ ọrọ yii nilu Ado Ekiti.

Awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti n ṣe ajọyọ afara ọkọ akọkọ iru ẹ ni ipinlẹ naa eleyi ti wọn ṣẹṣẹ ṣi ni ilu Ado Ekiti ni ala ọjọ ẹti.

Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan lo ṣi afara tuntun naa eleyi ti gomina ipinlẹ ọhun, Ayọdele Fayoṣe kọ si olu ilu ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, facebook/lere olayinka

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ Jonathan ní bí àwọn orílẹ̀èdè àgbáyé ṣe wá ń wẹnu sí Nàìjíríà lára kò dára

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ Jonathan ni asiko to fun awọn adari lorilẹede Naijiria lati mu idagbasoke ijọba tiwantiwa lskunkundun ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe.

Ọrọ aarẹ Jonathan ko ṣẹyin gbogbo pọpọṣinṣin idibo gomina nipinlẹ Ekiti eleyi to n bọ laipẹ.

Oríṣun àwòrán, facebook/lere olayinka

Àkọlé àwòrán,

Jonathan ní Nàìjíríà ti di àríwísí láwùjọ àgbáyé

O ni ohun to da oun loju ni pe 'pẹlu awọn akanṣe iṣẹ ti gomina Fayoṣe ti gbe ṣe ni ipinlẹ Ekiti, yoo ṣoro fun ẹgbẹ oṣelu miran lati gba akoso'nibẹ

O ni iwa awọn aṣiwaju lorilẹede naijiria ti sọ ọ di ariwisi ti ko tọna lawujs agbaye.

Oríṣun àwòrán, facebook/lere olayinka

Àkọlé àwòrán,

Jonathan ṣí afárá ọkọ̀ tuntun ní Adó Èkìtì

Afara ọkọ naa ni akọkọ ni ipinlẹ Ekiti latigba ti wsn ti daa silẹ lsdun 1996.

Gomina Fayoṣe ninu ọrọ tirẹ ṣalaye pe awọn iṣẹ ti iṣejsba oun gbe ṣe ko lee jẹ ko ṣeeṣe fun ẹgbẹ oṣelu kankan lati gba ijọba nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: