Lagos; Àwọn ará ìlú ló ni ohun amáyédẹrùn tó wà ní Eko

Aworan Ambode nibi ere idaraya losu to kọja.
Àkọlé àwòrán,

Gomina se ileri lati se awọn akanse isẹ tuntun mii

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ wi pe awọn ara ilu lo ni gbogbo awọn ohun amayedẹru ati dukia to wa ni ilu Eko.

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode sọ eleyii nibi igbaradi fun ayẹyẹ ọdun mọkanlelaadọta ti wọn da ipinlẹ Eko silẹ.

Ambode ninu ọrọ rẹ sọ wi pe ilu Eko ti rẹwa si ju ti ọdun to kọja lọ, nitori awọn isẹ akanse ti wọn sẹsẹ se si awọn agbeegbe ilu Eko.

Ijọba naa wa fikun wipe awọn ko ni dawọ isẹ duro ni ipinlẹ naa, ki igbe aye awọn eniyan ipinlẹ naa le rọrun ju ti atẹyin wa lọ.