JOHESU - Saraki yóò ríi pe ìyansẹ́lódì wọn parí

Sẹ́nétọ̀ Bukola Saraki
Àkọlé àwòrán,

Saraki yóò ríi pe ìyansẹ́lódì JOHESU parí

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà, Sẹ́nétọ̀ Bukola Saraki yóò sèpàdé pẹ̀lú àwọn adarí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera JOHESU lónìí ọjọ́ ajé.

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ń gbìyànjú láti fópin sí ìyansẹ́lódì ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera gùn le.

Ọ́fììsì tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìròyìn níle isẹ́ adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ló sọ wí pé ìpàdé náà yóò wáyé lọ́san òní.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Mẹkunnu loun jiya idasẹ silẹ Johesu - Ajafẹtọ ọmọniyan

Sẹ́nétọ̀ Saraki sọ pé ìpàdé náà yóò wáyé gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀lé èyí tó se pẹ̀lú Mínísítà fún ètò ìlera àti Mínísítà fún ọ̀rọ̀ òsìṣẹ́ lọ́jọ́ ẹtì.

Látinú osù kẹrin ni àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ti gùn lé ìyanṣẹ́lódì náà pẹ̀lú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ìjọ̀ba àpapọ̀ pé wọn kò se gẹ́gẹ́ bí àdéhùn tí wọ́n jọ se.

Ẹ̀sùn náà dá lórí àdéhùn wọn láti ọdún 2009 pàápàá èyí tí wọ́n se ní ọgbọ̀njọ́ osù kẹsan ọdún 2017 tó sì ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ márùn-ún sùgbọ́n tí ìjọba kò dáwọ́ lé.