Fayose ní òun yóó di ààrẹ tábí igbákejì ààrẹ ni 2019

Gomina Ipinlẹ̀ Ekiti Ayodele Fayose Image copyright LARU0004
Àkọlé àwòrán Fayose yoo fi ipò sílẹ̀ ní ọdun 2019

Ileéṣẹ́ ààrẹ orílẹ̀èdè Naijiria ti ní Gomina Ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayoṣe kò já mọ́ ẹni tí àwọn ń fún lésì látàrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó ní bí òun bá ti kúrò lórí àlèéfa ní ọdún tó ń bọ̀, òun yóó gba ipò Ààrẹ Muhammadu Buhari tábí igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo.

"Àwa kìí fesì sí Fayose" ni ohun tí agbẹnusọ ààrẹ, Femi Adesina, fi d'áhùn nígbà tí BBC kàn síi lórí ọ̀rọ̀ gómínà náà.

Fayose sọ níbi tí ó ti ń ṣi ọ́fíìsì gómínà tuntun ní Ado-Ekiti ní ọjọ́ ẹtì tó kọjá, "Oluwa Olorun ọ̀run ti sọ fún òun pé oun yóó di ààrẹ tábí igbákejì ààrẹ. Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni o. Ẹ lè gbagbọ́, ẹ lé má gbàgbọ́"

Bí ó ṣe sọ́ ọ̀ tán ni àwọn ará ìlú tó wà níbẹ̀ bú sẹ́rìń.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin tí kó ba fẹ́ òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì, ìpinu rẹ̀ mẹ́hẹ'