Onímọ̀ ní Nàìjíríà kò jàǹfàní ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé l'ábẹ́ Buhari

Buhari nibi ipolongo ibo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lai Mohammed ní ètò ọrọ̀ ajé ti padà sí ojú ọ̀nà ìdàgbàsókè, lẹ́yìn tó dagun láàrin ọdún 2016 sí 2017.

Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn ún ni àyájọ́ ọjọ́ ètò ìṣèjọba àwaará ní Nàìjíríà, tó sì tún jẹ́ ọdún kẹta tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ti wà ní orí àga ìṣàkóso.

Láti ìgbà tí ètò ìṣakóso nàá ti bẹ̀rẹ̀ ní oríṣiríṣi awuyewuye ti n wáyé lórí àwọn ẹ̀jẹ́ tí Buahri jẹ́ lásìkò ìpolongo ìbò tó ṣe ṣáàjú ètò ìdìbò gbogboogbo tó wáyé lọ́dún 2015, pàápàá lórí ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé, pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ṣe n sọ pé ìjọba Buhari kò ṣe tó.

Èyí n wáyé nítorí ìkọlù tí àwọn darandaran Fulani n ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí, àti ní pàtàkì, ìpínlẹ̀ Benue. Bákan nàá ni tí àwọn ìkọlù tí ikọ̀ Boko Haram n ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFayose sọrọ lori lẹta oloye Ọbasanjọ.

Èwo ni ìdáhùn

Ṣùgbọ́n, mínísítà fún ètò ìròyìn àti àṣà, Lai Mohammed, tako àríwísí àwọn tó ni ìṣàkóso Muhammadu Buhari, kò ní àṣeyọrí kankan láti fi hàn fún ọdún mẹta tó ti wà ní ipò.

O ni ètò ìṣàkóso nàá ti ṣe ju ohun tí àwọn ènìyàn lérò lọ, pàápàá mímú àyípadà bá ọ̀rọ̀ ètò ààbò, àgbénde ọrọ̀ ajé àti ìgbógun ti ìwà ìbàjẹ́, tó jẹ́ àwọn ohun tó ṣe kókó nínú ẹ̀jẹ́ tí Buhari jẹ́ lásìkò ìpolongo ìbò.

Ẹ̀wẹ̀, ó ní ''ètò ọrọ̀ ajé ti padà sí ojú ọ̀nà ìdàgbàsókè, lẹ́yìn tó dagun láàrin ọdún 2016 sí 2017."

Ṣùgbọ́n onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé, Kunle Olomofe, tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ní, ''lóòtọ́ ni ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti yípadà, ṣùgbọ́n, kò dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú. Bí i ti báwọ̀? Àlàyé n bẹ nínú fọ́nrán yìí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé sọ̀rọ̀ lórí ipò tí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà wà.

Ẹ̀wẹ̀, onímọ̀ kan nípa ètò ààbò, Ọ̀gbẹ́ni Richard Amuwa, sọ fún BBC Yoruba pé, "ohun tí àwọn ará ìlú n sọ ló yẹ kí ìjọba Buhari fi ṣe òdinwọ̀n àṣeyọrí ìṣàkóso rẹ̀, nítorí pé àwọn ló mọ bí ààbò ṣe wà fún ẹ̀mí àti dúkìá wọn."

Àti pé, ó yẹ kí Buhari ti pàárọ̀ àwọn olórí láwọn iléesẹ́ ètò ààbò Nàìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: