Osuntokun: Ó sàn kí ilé iṣẹ́ ààrẹ ka àwọn àṣeyorí rẹ̀

Àworan Ọbasanjọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Osuntokun ní, ó yẹ kí ilé-iṣẹ́ ààrẹ sàlàyé ohun tí wọn ti ṣe kí wọn le wọlé fún sáà ẹlẹ́keejì ni

Iná tí jó dé orí kókó lópin ọ̀sẹ̀ yìí nígbàtí Ilé iṣé Ààrẹ Muhammadu Buhari tú rúná sí àwọn ìṣesí Ààrẹ àná Olusegun Obasanjọ látẹ̀yìn wá gẹ́gẹ́ bíi agbẹ́nilẹ́sẹ̀.

Iná ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti ń rú láti bíi ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn nígbà tí Ọbasanjọ sọ pe Ààrẹ Muhammadu Buhari kò kún ojú òsùwọn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

#ShoMoAgeMiNi# Àṣà tó ń dá ìgboro rú

'Oró ejò ń sọ ènìyàn di aláàbọ̀ ara'

Olúwòó ti Iwo fakọ yọ nínú asọ ẹ̀yà Igbo

Ní báyìí, ilé iṣẹ́ ààrẹ ní kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ níyìí tí Obasanjọ tí ń tẹ ojú òfin mọ́lẹ̀ láti lé Gómìnà márùn-ún kúrò níjọba láti ọdún 1999-2007.

Garba Shehu tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ààrẹ sọ pé àsìkò Ọbásanjọ láààrin 1999-2007 jẹ àsìkò okùnkùn fún ìjọba àwa-ara wa nípa bí Ọbásanjọ ṣe ń tẹ ojú òfin mọlẹ̀.

Ó ní Ọbásanjọ máa ń lo irinṣẹ ìjọba láti fi bá àwọn Gómìna bíi Joshua Dariye, Rashidi Ladoja, Peter Obi, Chris Ngige àti Ayo Fayose jà látẹ̀yìn wá, àwọn olóṣèlú ọ̀hún jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau, Oyo, Anambra, Anambra àti Ekiti.

Lásìkò tí BBC Yorùbá bá agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú ADC Akin Osuntokun sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí agbẹnusọ fún ilé ààrẹ sọ yìí,

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsuntokun: Ó sàn kí ilé iṣẹ́ ààrẹ ka àwọn àṣeyorí rẹ̀.

Ó ní ọ̀rọ̀ tí kò mú ọgbọn dání ni, nítorí pé Ọbasanjọ ko dupo pẹlú Buhari bíkòṣe pe, ohún ṣe ìṣe àgbà kìí wà lọ́ja korí ọmọ tuntun wọ́.

Osuntokun ní, ó yẹ kí ilé-iṣẹ́ ààrẹ sàlàyé ohun tí wọn ti ṣe kí wọn le wọlé fún sáà ẹlẹ́keejì ni, kìí ṣe láti máa sọ ohun tí Ọbasanjọ ti ṣe lati ọdún tó ti pẹ́ sẹyìn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, isẹ ipese ina mọnamọna ni isejọba Aarẹ Ọbasanjọ lọdun (1999-2006) da owo le lasiko, sugbọn ti awọn ajafẹto omoniyan, Serap sọ wi pe, wọn se owó rẹ̀ basubasu.

Serap si kan si olootu eto idajọ lorilẹede Naijiria, Walter Onnoghen, lati se ọ̀fin toto bi wọn se naa owo naa.