Ben Murray-Bruce: ilé aṣòfin ń ṣàárò Dino Melaye

Aworan Dino Melaye Image copyright Instagram/dinomelaye
Àkọlé àwòrán Senatọ Dino Melaye farapa nigba ti àwọn agbófinró ń gbé e lọ sí Lọkọja

''Bó ṣe pé kí o tẹ pọ̀pá wa sí ijoko ilé aṣòfin, ri i wí pé o yọjú sílé lọjọ rú!''BEN

Senato Ben Murray-Bruce lo ke gbajare yii sí akẹgbẹ rẹ, Senato Dino Melaye, to n gba ìtọjú lọwọ nile ìwòsan.

Ojú òpó Twitter rẹ lo fi ọrọ náà lédè sí.

Ben Bruce ni lootọ lòún mò pé Senato Dino n tẹ pọpa ṣùgbọ́n ìtara àìsí ní ilé rẹ lo mu òun ke pè é.

''A n jarán rẹ ninu ilé. Ilé aṣòfin kò dùn pẹlú bí Dino kò ti ṣe sí níbẹ''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Loju òpó Twitter rẹ, Senato Dino Melaye ko fèsì bóyá òun yoo wa tàbí òun ko ni wá sugbọn o fi àwòrán ìwé àṣẹ ifi-muni ti awọn ọlọpaa mú wà láti wá fí tú ilé rẹ hàn fun ayẹwo ẹrù òfin.

O ni won ko ri nnkankan to lodi sofin ninu ile oun lẹyin ayẹwo wọn

Bí a kò bá gbàgbé, ilé Senato Dino àti ilé iṣẹ ọlópàá Nàìjíríà ti jọ n wọ ṣòkòtò kannáà lórí ẹsùn oríṣiríṣi tí wọn fí kàn an.

Láti ìgbà ti adájọ tí gbà oniduro rẹ ni Senato Dino Melaye ti wo ile ìsinmi.

O kàn ń fí ọ̀rọ̀ iṣiti ṣòwọ lórí Twitter ni, o dàbi pé, kò fẹ dá sí ọrọ ìṣèlú bí a ti ṣe mọ ọ sí tẹlẹ