Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí 'Democracy Day'

Asia Nigeria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nàìjíríà n ṣe àjọyọ̀ ọdún kejìdínlógún tí wọ́n ti n lo ètò ìṣèjọba àwaarawa.

Lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà n ṣe àjọyọ̀ ọdún kọkàndínlógún tí wọ́n ti n lo ètò ìṣèjọba àwa ara wa.

Àyájọ́ ọjọ́ nàá jẹyọ lọ́dún 1999, lẹ́yìn tí Nàìjíríà ti wà lábẹ́ ìṣàkóso ológun fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Bákan nàá ni ti ọdún 2018 n ṣe àmì ọdún mẹ́ta tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ti wà lórí àga ìṣàkóso Nàìjíríà, lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún tí Peoples Democratic Party, PDP, fi ṣèjọba.

Ṣíṣe àjọyọ̀ ètò ìṣèjọba àwa ara wa lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn ún ṣábà maa n fa àríyànjiyàn, pẹ̀lú bí èrò kálukú ṣe maa n ṣọ̀tọ̀ọ́tọ̀ lórí pàtàkì ọjọ́ nà.

Kín ni àwọn ọmọ Nàìjíríà n sọ?

Bí àwọn kan ṣe n rí ọjọ́ nàá bí ànfàání láti ṣàjọyọ̀ àwọ̀n nkan rere tó n jẹyọ lára irú ìṣèjọba bẹ̀ ẹ́, láwọn kan n takò ó pẹ̀lú àríyànjiyàn pé kò sí nkankan tó wú ni lórí, tó n pé fùn àjọyọ̀ ní Nàìjíríà, pàápàá nípa ìjọba rẹ̀.

Àwọn kan tilẹ̀ ní àkóba ni ètò ìṣèjọba àwaarawa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Bákan nàá, ni àwọn mì í tilẹ̀ di ẹ̀bi àwọn ìṣòro tí Nàìjíríà ní ru àwọn ọmọ orílẹ̀èdè ọ̀hún fún ra wọn, tí kií sì i ṣe ètò ìṣèjọba ọ̀hún tó ti mú ìdàgbàsókè bá àwọn orílẹ̀èdè mi í ní àgbáyé, tó sì ti gbá wọ́n kúrò lóko ẹrú, àti ìyà.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn kan ní ìjọba Muhammadu Buahri kó tì ṣe àsẹyọrí kankan láti ọdún mẹ́ta tó ti wà lórí àga ìṣàkóso, pàápàá lórí ètò ọrọ̀ ajé àti ààbò.

Láti ìgbà tí ètò ìṣakóso nàá ti bẹ̀rẹ̀ ní oríṣiríṣi awuyewuye ti n wáyé lórí àwọn ẹ̀jẹ́ tí Buahri jẹ́ lásìkò ìpolongo ìbò tó ṣe ṣáàjú ètò ìdìbò gbogboogbo tó wáyé lọ́dún 2015, pàápàá lórí ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé, pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà ṣe n sọ pé ìjọba Buhari kò ṣe tó.

Èyí n wáyé nítorí ìkọlù tí àwọn darandaran Fulani n ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí, àti ní pàtàkì, ìpínlẹ̀ Benue. Bákan nàá ni tí àwọn ìkọlù tí ikọ̀ Boko Haram n ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé sọ̀rọ̀ lórí ipò tí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà wà.

Ẹ̀wẹ̀, onímọ̀ kan nípa ètò ààbò, Ọ̀gbẹ́ni Richard Amuwa, sọ fún BBC Yoruba pé, "ohun tí àwọn ará ìlú n sọ ló yẹ kí ìjọba Buhari fi ṣe òdinwọ̀n àṣeyọrí ìṣàkóso rẹ̀, nítorí pé àwọn ló mọ bí ààbò ṣe wà fún ẹ̀mí àti dúkìá wọn."

Àti pé, ó yẹ kí Buhari ti pàárọ̀ àwọn olórí láwọn iléesẹ́ ètò ààbò Nàìjíríà.

Attahiru Jega pe àwọn Asòfin ní olè

"Ààrùn Ebola ti 'wá ni kòkòrò ajokorun"