Mozambique: Àwọn alákatakítí ẹlẹ́sìn bẹ́ orí ènìyàn mẹ́wàá

Àwọn ọmọ ogun Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni pé ẹgbẹ́ nàá n pá òbítí-bitì Dọla látara igi igbó àti òkúta olówó iyebíye.

Kò dín ní ènìyàn mẹ́wàá tí wọ́n bẹ́ lórí lórílẹ̀èdè Mozambique.

Òṣìṣẹ́ ìjọba kan lẹ́kùn Palma, tó wà ní àgbègbè Cabo Delgado, fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá múlẹ̀, ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Ẹgbẹ́ kan tí wọ́n mọ̀ lábẹ́lé sí al-Shabab tàbí al-Sunna, bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn lọ́dún 2015, ṣùgbọ́n tó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọlù láàrin ọdún kan péré.

"Ìjọba tiwa n' tiwa ; Ṣé ó yẹ láti ṣàjọyọ̀?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyájọ́ ọjọ́ ìjọba Tiwa n' tiwa, kí la ti se?

Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni pé ẹgbẹ́ nàá n pá òbítí-bitì Dọla látara igi igbó àti òkúta olówó iyebíye.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ṣáláàṣí ni àwọn aláṣẹ orílẹ̀èdè Mozambique ti tì pa báyìí.