‘Iléesẹ́ Visionscape kò ló jẹ agbálẹ̀ lówó osù’
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Visionscape: Abẹ́ iléesẹ́ wa kọ́ làwọn agbálẹ̀ wà

Olórí ẹ̀ka ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fún iléesẹ́ Visionscope ní ìpínlẹ̀ Èkó, Motunrayọ Elias, nínú ifọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC Yorùbá ní, iléesẹ́ Visionscape kọ́ ló gba àwọn agbálẹ̀ tó fi ẹ̀hónú hàn láìpẹ́ yìí sẹ́nu isẹ́.

Ó ní iléésẹ́ Standard Street Manpower Limited ló gba àwọn òsìsẹ́ náà sẹ́nu isẹ́, nítorí náà, kìí se iléesẹ́ Visionscape ló jẹ wọ́n lówó osù.

Elias fi kun pé àwọn gan ń wá àwọn alásẹ iléesẹ́ Standard Street Power Limited láti mọ ohun tó sẹlẹ̀, tí wọn fi jẹ àwọn agbálẹ̀ náà lówó.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: