CAN: Ó pọn dandan kí wọn fágile ìdánwò ọlọ́pàá

Ilé ìjọsìn Image copyright Dan Kitwood
Àkọlé àwòrán Ẹ́ fágile ìdánwò ọlọ́pàá

Agbarijpọ ẹgbẹ awọn onígbàgbọ́ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (CAN), tí ké gbànjarè pé, kí àjọ ọlọ́pàá fagilé ìdánwò gbogbo-gboo fún ìgbanisíṣẹ́ to wayé láìpẹ́ yìí jakèjádò Nàìjíría.

Àjọ CAN gùnlé ọ̀rọ̀ òhún nítorí awuyewuye tó súyọ lẹyìn tí ìdánwò náà parí, wípé, wọn fi èdè Arabic sínú ìbéèrè tí wọn ṣe fún awọn olùkọpa náà

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn òṣìṣẹ́ tí o ń gbá títì olọ́da ní Ékó fẹ̀hónú hán ní ọ́fìsì Visionscape
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Isẹ́ Tíátà tí mò ń se ti tó mi jẹun'

Agbenusọ fún ààrẹ àjọ CAN ní Nàìjíría, Adebayo Oladeji sọ fún BBC Yorùbá pé, '' fífi Arabic sínú ìdanwò ìgbaniwọlé sí iṣẹ́ ọlọ́pàá jẹ́ ọnà láti dín ànfààní àwọn kristẹni kú fún ìgbanisíṣẹ́ náà"

"Ó pọndandan kí àjọ ọlọ́pàá fagilé ìdánwò ọ̀hún"

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: ó pọn dandan kí wọn fágile ìdánwò ọlọ́pàá

Bákan náà ní Ọ̀jọ̀gbọn Charles Adisa, to bá BBC Yoruba sọrọ sàlàyé pé, lẹyìn tí òun gbọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní òun fi ìpè síta láti wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀.

Ó ní òun se iwadii oun laarin àwọn tó ṣe ìdánwò ní Port Harcourt, Gombe, Osun àti Umuahia, tí wọn sì jẹ́rìí pé, Arabic wà nínú ìdáwò náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: ó pọn dandan kí wọn fágile ìdánwò ọlọ́pàá

ní ìhà tí Àjọ JAMB kọ sí ọ̀rọ̀ náà:

Fabian Benjamin, tó jẹ agbẹnusọ fún àjọ JAMB, nínú àtẹjáde kan sàlàyé pé, ìyàlẹnu ló jẹ láti máa gbọ pé àjọ JAMB ló èdè Arabic láti fí dán àwọn olùkópa wò.

"Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní òtítọ́ nínú, tò sì jé ohun ìṣìnà pátápátá. Igbọra ẹni ye wà pé èdè gẹ̀ẹ́sì nìkan ní kí wọn dahun sí"

Ìgbìyànjú wa láti bá ileesẹ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ ló já sí pàbó nitori agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọ́pàá, Moshood Jimoh, kò gbé ẹrọ ibara ẹni sọrọ ti a fi pee.