Koko ìròyìn: Democracy Day lorilẹede Naijiria, Kewu ati Idanwo ọlọ́pàá

Eyi ni akójọpọ̀ àwọn ìròyìn ti toni.

Àyájọ́ ọjọ́ ìjọba Tiwa n' tiwa: Kókó mẹ́wàá nínú ọ̀rọ̀ Buhari

Àkọlé fídíò,

Àyájọ́ ọjọ́ ìjọba tiwa n' tiwa: Kókó 10 nínú ọ̀rọ̀ Buhari

Lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà n ṣe àjọyọ̀ ọdún kọkàndínlógún tí wọ́n ti n lo ètò ìṣèjọba àwa ara wa.

Àyájọ́ ọjọ́ nàá jẹyọ lọ́dún 1999, lẹ́yìn tí Nàìjíríà ti wà lábẹ́ ìṣàkóso ológun fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Bákan nàá ni ti ọdún 2018 n ṣe àmì ọdún mẹ́ta tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ti wà lórí àga ìṣàkóso Nàìjíríà, lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún tí Peoples Democratic Party, PDP, fi ṣèjọba.

CAN: Ó pọn dandan kí wọn fágile ìdánwò ọlọ́pàá

Aworan Asia olopaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀jọ̀gbọn Charles Adisa to bá BBC sọrọ sàlàyé pé lẹyìn tí òun gbọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní òun fi ìpè síta

Agbarijopọ ẹgbẹ awọn onígbàgbọ́ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (CAN), tí ké gbànjarè pé kí àjọ ọlọ́pàá fagilé ìdánwò gbogbo-gboo fún ìgbanisíṣẹ́ to wayé láìpẹ́ yìí jakèjádò Nàìjíría.

Àjọ CAN gùnlé ọ̀rọ̀ òhún nítorí awuyewuye tó súyọ lẹyìn tí ìdánwò náà parí, wí pé, wọn fi èdè Arabic sínú ìbéèrè tí wọn ṣe fún awọn olùkọpa náà. E ka ekunrere re ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Kayọde Oduoye: Àwọn àgbààgbà tó ti sèjọba kọjá yẹ kó lọ sinmi

Àkọlé fídíò,

Odùoyè: Àwọn àgbààgbà tó ti sèjọba kọjá yẹ kó lọ sinmi