Àwọn ọmọ ilé aṣòfin Nàìjíríà fèsì lórí ẹ̀sùn gbígba rìbá tí Jega fi kàn wọ́n

Ile Igbimọ Asofin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn Asòfin nà ní kí Jega gbé orúkọ àwọn tó n gbowó ẹ̀yìn síta

Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ti fèsì sí ẹ̀sùn tí alága àjọ INEC nígbà kan rí, Attahiru Jega, fi kan àwọn aṣòfin.

Láìpẹ́ yìí ni Jega, níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tó ṣe láti ṣààmì àyájọ́ ọjọ ìṣèjọba àwa ara wa ní ìlú Abuja, ní àwọ̀n ọmọ ilé aṣòfin Nàìjíríà fẹ́ràn láti maa gba owó ní ọ̀nà ẹ̀bùrú, kí wọ́n ó tó ṣe iṣẹ́ wọn.

Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni àwọ̀n aṣòfin fún Jega ní èsì ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdùoyè: Àwọn àgbààgbà tó ti sèjọba kọjá yẹ kó lọ sinmi

CAN faraya lórí fífi kéwú kọ ìdánwò ọlọ́pàá

Àwọn asòfin tó de ìdí fún ìsúná 2016 wọ gàù

Ìwé ìròyìn Vanguard jábọ̀ pé àwọn aṣòfin láti ilé aṣofin méjèéjì panu pọ̀ láti sọ pé, kí Attahiru Jega fi orúkọ àwọn aṣòfin tó jẹ̀bi ẹ̀sùn nàá sí ta láti lè gbe ẹ̀sùn tó fi kàn wọ́n lẹ́sẹ̀.

Àti pé, ọ̀rọ̀ nàá dàbíì ẹni tó n yọ èrúnrún igi lójú ẹlòmíì, láì yọ ìtí igi tó n bẹ lójú ara rẹ̀. Ìròyìn nàá sọ pé, akójàánu fún ilé aṣòfin àgbà, Sẹnetọ Olusọla Adeyẹye ní '' kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ yóò jẹyọ, àti pé ẹni tó fún ni ní owó ẹ̀yìn, tó fi mọ́ ẹni tó gbà á, ló jọ jẹ̀bi ìwà ìbàjẹ́ náà.