Mnangagwa: Oníkálukú yóò yàn ẹni tó fẹ́ sípò tó wù ú

Asia Zimbabwe Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Zimbabwe yóò dìbò lọjọ Aje, ọgbon ọjọ́, osù keje, ọdun 2018

Ìdìbò yìí ni àkọkọ iru rẹ lẹyin ti Robert Mugabe kúrò lori àlééfà ni Zimbabwe

Aare Emmerson Mnangagwa to ń tukọ orilẹ-ede Zimbabwe lọwọ lo kede ètò idibo naa.

Awọn ènìyàn ilẹ̀ Zimbabwe yóò ni anfani lati dibo yan aarẹ, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ati àwọn kansilọ wọ́ọ̀dù kọọkan to ba wu wọn si ipo ti wọn fẹ.

Oṣù kọkanla ọdun to kọja ni Aarẹ Mnangagwa gori aleefa pẹlu iranlọwọ àwọn ológun nigba ti wón gba ijọba lọwọ Robert Mugabe.

Ọpọ àwọn ènìyàn ilẹ Zimbabwe ri ikede yii gẹgẹ bi igbesẹ si iṣejọba to munadoko ni èyí ti yoo bi idagbasoke to yẹ ti idibo naa ba waye láìsí wahala kankan.

Aarẹ Emmerson Mnangagwa jẹ ọmọ ọdun marundinlọgọrin bayii.

O ti ṣeleri pe eto idibo naa ko ni ni kọ́núunkọ́ọ kankan ninu.

Ọmọ ogoji ọdun, Nelson Chamisa, to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu 'The Movement for Democratic Changes' ni o jẹ olori alatako fun Emmerson Mnangagwa.

Morgan Tsvangirai to doloogbe loṣu keji ọdun yii lo ti jẹ olori ẹgbẹ oṣelu 'The Movement for Democratic Change' fun ọdun pipẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?