Oluwo: Ọpọ̀ àṣà àdáyébá tó ti dogbó, ló yẹ kí Aláàfin yípadà

Oluwo àti Alaafin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alaafin

Àkọlé àwòrán,

Ade yoo pẹ lori fun Alaafin Ọyọ

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba AbdulRasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, ti ransẹ ikini si Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, lori ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun rẹ.

Bakan naa ni Oluwo tun gba Alaafin nimọran pe, ni bayii to ti pẹ lori oye, o yẹ ko ri daju pe awọn asa adayeba kan ti ọjọ ti lọ lori wọn nilẹ Yoruba, ni atunse ba, paaà ipo tawn olori ọba wa.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Oluwo ti Iwo Ọba AbdulRasheed Akanbi kí Aláàfin Ọyọ kú ọjọ́ ìbí

Oluwo wa fi awọn olori laafin se apẹrẹ, awọn to ni olori obinrin ni wọn jẹ, o si yẹ ka gba wọn laaye lati maa dade bii Ọbabinrin nilẹ Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìjọba Ọ̀yọ́: Kò sí ilé kan tí wọn kò tíì bí ìbejì ní Igbó Ọrà

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwo sọ pe, o wa ninu itan iṣẹdalẹ Yoruba pe, Olokun to jẹ iyawo Oduduwa de ade.

Oluwo ni bi a ti n fi ade mọ ọba nilẹ Yoruba, bẹẹ gẹgẹ lo yẹ ki a maa fi ade mọ awọn olori naa.

Oluwo wa gbadura pe Ọba Lamidi Adeyẹmi yoo lo aadọta ọdun laye si ati lori itẹ baba rẹ.

Oríṣun àwòrán, FunmiSodiq

Àkọlé àwòrán,

Ọba Àkànbí ní iìjọba leè dá àjọ kan sílẹ̀ láti gbógun ti ìwà ẹgbẹ́ òkùnkùn

Oluwo tako ẹgbẹ́ òkùnkùn

Ijọba gbọdọ da ajọ kan silẹ ti yoo koju iwa ẹgbẹ okunkun lawujọ.

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi lo sọ bẹ nilu iwo.

Àkọlé fídíò,

Olúwòó ní àwọn Ọba ń se ẹgbẹ́ òkùnkùn

Ọba Akanbi ni gulegule ẹgbẹ okunkun lawujọ n fẹ amojuto to jọju bayii.

O ni didẹkun iwa ibajẹ naa lawujọ, yoo nilo ki awọn Ọbalaye, oloṣelu ati aṣiwaju awujọ gbogbo pẹlu paramọ kuro ninu ẹgbẹ okunkun ṣiṣe.

Oríṣun àwòrán, FunmiSodiq

Àkọlé àwòrán,

Ọba Àkànbí ní iìjọba leè dá àjọ kan sílẹ̀ láti gbógun ti ìwà ẹgbẹ́ òkùnkùn

Olúwo ni pupọ awọn Ọbalaye ati oloṣelu ni wọn wa lẹgbẹ okunkun, ti wọn ko si lee ko awọn ọdọ to n ṣe ẹgbẹ buruku naa nijanu.

"Nigba ti a ba n bu awọn ọdọ pe wọn n dara pọ mọ ẹgbẹ okunkun, ti awọn agba pẹlu, paapaa awọn lọbalọba pẹlu tun n ṣe ẹgbẹ okunkun.

Gbogbo awọn lọbalọba ati oloṣelu gbọdọ kuro lẹgbẹ okunkun ki wọn lee ba awọn ọdọ to n ṣe ẹgbẹ naa wi."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni Ọba Akanbi tun pe fun idasilẹ ajọ kan ti ojuṣe rẹ yoo wa lati maa gbogunti iwa ẹgbẹ okunkun lawujọ laarin awọn ọdọ ati awọn agbablagba.

"Gbogbo awọn ofin to de iwa ẹgbẹ okunkun lawọn ọgba ileẹkọ, lawọn agbofinro ni lati gbe ko awọn agbaagba, awọn oloṣelu atawọn lọbalọba to n ṣe ẹgbẹ okunkun yii, loju.

Ijọba si gbọdọ da ajọ kan silẹ lati gbogun ti ẹgbẹ okunkun ṣiṣe."