Ilé ẹjọ́ ju gómínà àná ní Kaduna, Ramalan Yero s'átìmọlé

Ramalan Yero

Oríṣun àwòrán, @MobilePunch

Àkọlé àwòrán,

Yero jẹ́ gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàrin 2012 sí 2015

Ramalan Yero àti àwọn mẹ́ta míì ni adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ẹ̀sùn tí àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́, EFCC, fi kàn wọ́n.

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna tí ju gómìnà nígbà kan rí s'atimọle títi ìgbẹjọ yoo fi pari.

Àwọn mẹ́ta ọ̀hún ni mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèérè nígbà kan rí, Nuhu Way, tó fi mọ́ ẹni tó ti fígbà kan jẹ́ akọ̀wé fún ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna, Hamza Ishaq, àti alága ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party fún ìpínlẹ̀ Kaduna nígbà kan, Abubakar Gaya Haruna.

Yero tó jẹ́ gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàrin 2012 sí 2015 ni àjọ EFCC fi ẹ̀sùn lílú owó tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin mílíọ́nù Naira, 700 Million Naira ní pónpó.

Ṣáàjú àsìkò yí ni EFCC tí n wádìí gómínà ọ̀hún fún ipa tó kó nínú níná àti pínpín owó náà tó jẹ́ owó ìpolongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lásìkò tí ìdìbò gbogboogbo ọdún 2015 kù díẹ̀.

Oríṣun àwòrán, @EFCC

Àkọlé àwòrán,

Ẹsun ṣiṣe owọ ilu kumọkumọ ni wọn fi kan Yero

Adájọ́ àgbà ní ilé ẹjọ́ náà, Onídàjọ́ Mohammed Shuaibu, ní kí àwọn olùjẹ́jọ́ náà wà ní atimọle títí di ọjọ́ kẹfà, oṣù Kẹfà.

Èyí wáyé lọjọ́ keji tí ilé ẹjọ́ jú gómìnà àná fún ìpínlẹ̀ Taraba, Jolly Nyame sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá, fún ipa tó kó nínú bí N1.64billion ṣe di àwátì lásìkò tó fi jẹ́ gómìnà láàrin ọdún 1999 sí 2007.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?