Dino: Kò tọ́ bi Buhari se tàbùkù ilé aṣòfin

Aworan Senato Dino

Oríṣun àwòrán, Voice TV

Àkọlé àwòrán,

Senato Dino Melaye ni oun fẹ kí Ààrẹ Buhari tọrọ aforijin lọwọ ilé

Senato Dino Melaye tutọ soke fojú gbàá, tó sì bẹnu àtẹ lù ààrẹ orílèèdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari.

O ní ọrọ tí ààrẹ sọ pé àwọn aṣòfin kan joko sile fún ọpọ ọdún, láì fi aba kánkan ṣòwò ku diẹ kaato.

Melaye ni, òkun ọrun ko ye adiẹ, nítorí náà kò tọ́ bi Aare Buhari ṣé sọ iru ọrọ bẹẹ sì àwọn aṣòfin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Níbo ní Buhari tí sọ ọrọ̀ náà

Gẹ́gẹ́ bí Dino ti ṣe sọ, ọ ni Ààrẹ sọ ọrọ náà nígbà tí o gba àlejò awọn ọmọ ẹgbẹ tó n ṣé ìpolongo fún ùn Buhari (Buhari Campaign Organisation), ti olórí ilé iṣé aṣobode, Ọgagun Hameed Ali ko sódì.

''Ipò ni Ọgá ile iṣẹ asobode. O lòdì s'ofin ki oga ile iṣẹ aṣobode máa polongo fún Ààrẹ.''

''Mo ti wa ni ilé fún nnkán bi ọdún mọkanla sẹyìn. Se Aare Donald Trump yóò sọ iru ọrọ yi sile asofin ile Amerika?''

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán,

Òwúrọ̀ Ọjọ́rú ni Melaye padà sí ilé aṣòfin lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé láàrin òun àti àwọn ọlọ́pà

Senato Dino ni, kò yá òun lẹnu pé àwọn tí Ààrẹ je oga fún kọ láti yọjú sí ilé

''Fèré ti olówó wọn n fọn sinu wọn, ni wọn n fọn sita.''

Fidio ọrọ rẹ ree loju opo Twitter.

Ààrẹ buwọ́lù abadofin mí

Ko tan sibẹ. Dino kin ọrọ re lẹyin pẹlu abadofin tuntun ti Aare Buhari buwolu.

''Èmí ni mo se atona abadofin ti o faaye gbà àwọn ọdọ láti du ipò tí o bá wù wọ́n èyí tí ààrẹ buwọ́lù.''

''Bí Ààrẹ bá fẹ mo òun ti a n ṣe, ara rẹ ni abadofin náà''

Oríṣun àwòrán, facebook/Dino Melaye

Àkọlé àwòrán,

Senato Dino Melaye ni oun fẹ kí Ààrẹ Buhari tọrọ aforijin lọwọ ilé

Lẹnu ọjọ mẹta yìí, Senato Dino Melaye àti ilé iṣé ọlọ́pàá, to fi mọ Gómìnà ipinle rẹ Kogi, ti n bá ará wọn fà wàhálà.

Ọrọ rẹ pada de ilé ẹjọ ṣugbọn lẹyìn ọpọ atotonu, adájọ gba oniduro rẹ̀.

Àwọn onwòye ní, inú Senato Dino kò dùn sí bí ẹgbẹ oselu APC pàápàá jùlọ Ààrẹ Buhari, kò ṣé kò ọgá ọlọ́pàá ni ijanu lórí ọrọ rẹ.