Uganda: Á lo owọ́ orí náà láti san gbèsè táa jẹ

Àmì ìdámọ̀ Whatsapp

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Igba ṣílẹ̀, eyiun dọ́là márùn-ún àbí pọ́ùn mẹ́rin, làwọn èèyàn tó bá ń lo Whatsapp àti Facebook yóò máa san

Ilé asòfin lórílẹ̀-èdè Uganda ti buwọ́lu òfin kan tó ń fa awuye-wuye èyí tó ní káwọn èèyàn tó ń lo ojú òpò ìkànsíraẹ́ni lórí ìtàkùn àgbáyé bíi Whatsapp àti Facebook máa san owó orí.

Igba ṣílè, eyiun dọ́là márùn-ún àbí pọ́ùn mẹ́rin, làwọn èèyàn tó bá ń lo àwọn ojú òpó wọ̀nyí lórí ìtàkùn àgbáyé yóò máa san lójoojúmọ́, tí wọn bá sí Facebook, Whatsapp, Viber àti Twitter.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àarẹ̀ Yoweri Museveni ti orílẹ̀èdè Uganda ló se agbátẹrù òfin náà pẹ̀lú àwíjàre pé àwọn ojú òpó ìkànsíraẹ́ni náà máa ń se kóríyá fún ìwà gbéborùn àbí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Uganda nílò owó orí náà láti fi san díẹ̀ lára gbèsè tó jẹ

Ọjọ́ kìnní osù keje ọdún 2018 ni òfin náà yóò fẹsl múlẹ̀ sùgbọ́n iyèméjì wà lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbà se àmúsẹ rẹ̀.

Mínísítà abẹ́lé fétò ìsúná ní Uganda, David Bahati sọ fáwọn asòfin náà pé ìjọba nílò owó orí náà, láti fi san díẹ̀ lára gbèsè tí orílẹ̀èdè náà jẹ, èyí tó ń rú gọ́gọ́ síi.