Johesu: A so ìyansẹ́lódì rọ̀ kí ìjíròrò leè já gaara

Aworan ile iwosan

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Iyansẹlodi lẹka ilera orileede Naijiria ki se ohun tuntun mọ

Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera lórílẹ̀èdè Naijiria, labẹ àsìá ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn òṣiṣẹ́ ìlera JOHESU fòpin sí iyansẹlodi wọn lónìí.

Adarí ẹgbẹ́ JOHESU, Josiah Biobelemoye, sọ ní Abuja lọ́jọ́bọ́ pé, àwọn so yanṣẹ́lódì náà rọ̀, láti lè jẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lọ déédé lórí àwọn oun tí wọ́n n béérè.

Biobelemoye ní kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ JOHESU padà sí ẹnu íṣẹ́ ní ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Àwọn aláìsàn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹgbẹ́ JOHESU

Iyanṣẹ́lódì Johesu ti pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lbáyìí, bẹ́ẹ̀ bá sì gbàgbé, osu kẹwa ọdún tó kọjá ni awọn dókítà orileede Naijiria, sapèjúwe ẹgbẹ àwọn oṣiṣẹ ilera Johesu gẹgẹ bii "ajo ti ko bofinmu".

Wọn ni ọpọ òun ti Johesu n béèrè fún ko bójú mu.

Iyanṣẹ́lódì lẹ́ka ìlera Naijiria kìi ṣe ohun tuntun mọ́, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ilé ìwòsan ni ó ti ní àwọn yóò lé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Johesu lẹ́nu iṣẹ́, tí wọn ko bá padà fòpin sí ìyanṣẹ́lódì náà.