Dangote ni ìdàgbàsókè ẹ̀ka ọ̀gbìn ti mú àwọn agbẹ gòkè àgbà

Buhari pẹlu awọn oniṣowo l'Abuja Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Bí Nàìjíríà bá tẹra mọ́ ìdàgbàsókè ẹ̀ka ọ̀gbìn, yóò leè bọ́ ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà lapapọ

Olokoowo to lowo ju ni Afirika, Aliko Dangote, ti fi ọrọ ẹri lelẹ pe nnkan ti n sẹnuure fawọn agbẹ lorilẹ-ede naijiria.

Dangote ni awọn agbekalẹ ilana ati eto iṣejọba ti Aarẹ Buhari gbe kalẹ ti ro awọn agbẹ lagbara ti awọn pẹlu si lee fi ọwọ sọya lawujọ pe iṣẹ ọwọ wọn n to wọn jẹ ti wọn si fi n pa owó sapo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dangote mẹnu le ọrọ lasiko to fi kọwọrin pẹlu awọn oniṣowo jankanjankan lorilẹ-ede Naijiria lọ sibi apejẹ iṣinu awẹ eleyi ti aarẹ Buhari ṣeto ni lu Abuja.

"Eto ọrọ aje ti n pada bọ sipo, owo wa si ti i burẹkẹ sii lojoojumọ; nnkan yoo tubọ maa se rẹgi lorilẹ-ede yii.

Iṣoro ati idamu ti awọn ileeṣẹ la kọja lọdun 2016 si 2017 ti di ohun igbagbe bayii."

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán "Iṣoro ati idamu ti awọn ileeṣẹ la kọja lọdun 2016 si 2017 ti di ohun igbagbe"

O ni yoo dara pupọ bi ijọba ba n tẹsiwaju lati yẹ awọn ẹka miran yatọ si epo rọbi wo fun idagbasoke eto ọrọ aje.

Bakan naa lo tun ni awọn agbẹ ti di ọba bayii ti apo wọn gan ti wu soke ju ti awọn oṣiṣẹ ijọba gan an lọ.

O ni orilẹ-ede Naijiria lee bọ gbogbo ẹkun iwọ oorun Afirika bi awọn adari rẹ ba gbajumọ idagbasoke eto ọgbin.