Tramadol: Orísun ikú, àìní-rètí àti Boko Haram

Àwọn ọkùnrin méjì tó ń ki ìbọn
Àkọlé àwòrán,

Ìlú Maiduguri ló ń forí sọta làásìgbò Boko Haram fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún - bákan náà ló tún ń ja ìjà abẹ́nú pẹ̀lú àsìlò òògùn

Òògùn Codeine nìkan kọ́ ni òògùn táwọn èèyàn sọ di bárakú jákè-jádò ẹkùn ìwọ̀ òòrùn Afrika. Òògùn araríro míì, Tramadol, náà sì ń tàn kálẹ̀, bíi òògùn táwọn èèyàn ń sì lò - gẹ́gẹ́ bi akọ̀ròyìn BBC, Stephanie Hegarty se sàwárí rẹ̀, èyí tún leè ta epo pẹtiroolu sí ina ìgbésúnmọ̀mí tó ń jó ní ìlú Maiduguri.

Nígbà tí Mustapha Kolo, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún mu òògùn pupa tó dùn wò lójú náà, ó dà bíi pé ó leè hú igi. Bíí ìgbà tí ara rẹ̀ kìí se tiẹ̀. Ó sì ń mú èrò burúkú jáde.

"Tí mo bá ti múú, mo máa ń gbàgbé gbogbo nkan ni."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Fídíò òògùn ikọ́ Codeine: Ó dùn lóòtọ́ àmọ́ ewu ni

Ojú Kolo dúdú, tó sì pọ́n bíi ẹ̀yẹ iná, ohùn rẹ̀ ń lọ́ pọ̀, tí kò sì já gaaraga bó se ń sọ̀rọ̀. Ọ̀rẹ́ rẹ̀, Modu Mustapha ni kò mọ ohun tó ń se mọ́, tí orí rl sì ń mì dirọ̀-dirọ̀ ní ààrin èjìká rẹ̀ tó jk kìkì eegun.

Ó fojú hàn gbangba pé irọ̀ ni wọ́n ń pa, tí olórí wọn, tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi fijilante tó ń sọ́ ìlú Maiduguri, sì rọ̀ wọn láti sọ tòótọ́.

"Tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀, mo máa ń mu tó mẹ́ta tàbí mẹ́rin nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní muú. Sùgbọ́n ní báyìí, mo ti dínkù sí ẹyọ kan tabi ààbọ̀", tí Kolo kò sì setán láti sọ̀rọ̀ síwájú.

Àkọlé àwòrán,

Mustapha Kolo ní òògùn oníhóró náà máa sèrànwọ́ tóun bá wà nínú igbó láti bá Boko Haram ja

Ní ìlú tí kò fararọ yìí, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn ni òògùn olóró Tramadol ti di bárakú fún - àwọn ẹ̀sọ́ fijilante, àwọn tí ogun le nílé àti àwọn adúnkookò gan fún ra wọn.

Òògùn aporó tí kò wọ́n rara yìí wà láti wo ara ríro níwọ̀n ba. Sùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bó se máa ń rí pẹ̀lú àwọn òògùn olóró, èèyàn leè kúndùn rẹ̀, kó sì di bárakú sí onítọ̀ún lára - sùgbọ́n àríyàn-jiyàn sì ń wáyé lórí bí èèyàn se leè kúndùn rẹ̀ sí.

Àjọ elétò ìlera lágbàáyé (WHO) ní Tramadol làwọn èèyàn lérò pé ó "èèyàn leè má tètè kúndùn rẹ̀ táa fi wé Morphine"

Àmọ́ bí ọwọ́jà òògùn náà se ń jà rànìn-rànìn káàkiri ẹkùn ìwọ̀ òòrùn Afrika tako èrò yìí.

Àkọlé àwòrán,

Bí àwọn ọmọ Nàíjíríà se kúndùn òògùn lílò ti di ìràwọ̀ ọ̀sán, tó ń ba àgbà lẹ́rùn báyìí - àjọ ìsọ̀kan àgbáyé sì fẹ́ se ìwádìí lópin ọdún yìí

Àwọn olórí àtàwọn ológun ni wọ́n se Tramadol fún, àmọ́ bí àwọn àdúnkookò-mọ́ni se wá kúndùn rẹ̀ láti máa gbẹ̀mí ẹni, wá di àpérò àwọn ọmọ eríwo báyìí, èyi tí wọn ló ń dákún bí ọwọ́jà wọn se ń le koko síi.

Ọ̀kan lára àwọn agbébọn tẹ̀lẹ̀, tíí se ẹni ọdún mọ́kànlélógún, tó wà ní àgọ́ àwọn ológun ilẹ̀ Nàíjíríà, lẹ́yìn tó ti sá ní àgọ́ Boko Haram lósù kínní 2018, sàlàyé pé ọdún mẹ́rin ni òun fi gbé inú igbó níbi tí kò sí omi tó tó tàbí oúnjẹ - sùgbọ́n Tramadol wà.

"Tá a bá ń lọ se ìkọlù wa, wọn yóò fún wa ní òògùn náà láti lò, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tó o bá mu ú, wọ́n leè pa ọ́. Wọ́n sọ fún wa pé tí o bá ti mu òògùn náà, ẹ̀rù kò ní bà ọ́ ma, ó ní agbára àti okun síi. Òògùn áà pọ̀ ní àpsjù."

Àkọlé àwòrán,

Àwọn olórí àtàwọn ológun ni wọ́n se Tramadol fún

Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Àyúbà ti wí, "kò sẹ́ni tó leè pa èèyàn lójú lásán, sùgbọ́n òògùn Tramadol wà níbẹ̀ láti tìẹ́ sisẹ́ ibi."

Àwọn obìnrin kan wà tí wọn ti sá kúrò ní ibùba Boko Haram, àmọ́ tí òògùn olóró ti di bárakú fún nítorí ń se làwọn àdúnkookò-mọ́ni náà máa ń lo òògùn fáwọn ọmọdebìnrin náà tí wọn bá ti ń sunkún."

Àjọ ìsọ̀kan àgbáyé ní, àwọn ikọ̀ ọ̀daràn lágbàáyé ló ń kó Tramadol wọ ilẹ̀ Afrika láti ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Asia. tí àwọn agbófinró sì ń gbẹ́sẹ̀ lé ìwọ́n kílò tó tó ọ̀ọ̀dúnrún ní ọdọọdún.

Àkọlé àwòrán,

Àjọ ìsọ̀kan àgbáyé ní, àwọn ikọ̀ ọ̀daràn lágbàáyé ló ń kó Tramadol wọ ilẹ̀ Afrika láti ẹkùn gúúsù ilẹ̀ Asia

Ní báyìí tí ìlòkulò Tramadol ń wáyé ní Nàíjíríà, ó nira púpọ̀ láti mọ ìdí tí wọ́n se gbé Tramadol sí abẹ́ àwọn òògùn olóró bíi oxycontin, morphineàtàwọn òògùn olóró míì bíi Cocaine ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà.