Shina Peller: Afojúsùn mi ni kí gbogbo ènìyàn jẹ mùdùn-múdùn ìjọba

Gbajúgbajà onísòwò, Shina Peller Image copyright @ShinaPeller
Àkọlé àwòrán Ọmọ Prof. Peller gbé 'gbá ìbò fún 2019

Alága ilé isẹ́ Aquilla Group, Olóyè Shina Peller ti kéde pé òun yóò du ìpò asojú ní ilé ìgbìmọ̀ asojúsòfin nínú ètò ìdìbò tó m bọ̀ lọ́dún 2019.

Shina Peller to jẹ́ ọmọ bíbí inú gbajúgbajà onídán tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Professor Peller ní òun yóò díje láti sojú kùn ìdìbò Iseyin, Itesiwaju, Kajola àti Iwajowa ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àwọn tó ní dandan àfi kí Shina Peller rawọ́lé òsèlú sọ pé àksìkò tó kí àwọn ará Ọ̀yọ́ wá ọ̀dọ́ tó sì ní òye sínú ìjọba fún ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n ti rọ òun láti lo ànfàní pé ó jẹ́ gbajúgbajà mí ìpínlẹ̀ náà fún òsèlú sùgbọ́n tí kò tíì pinnu lọ́kàn rẹ̀.

Shina ti fi ìgbà kan f'èsì wí pé "ní báyìí, òwò mí ló jẹ́ àkọ́kọ́ lọ́kàn mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn mi ń fàmi n''ihìín lọ́hùún láti dara pọ̀ mọ́ òsèlú, sùgbọ́n mi ò tíì pinnu ọkàn mi"

Ọmọ bíbí ìsẹ́yìn náà sọ pé láti ìgbà tí 'ti wà nílé ìwé gíga fásitì Ladoke Akintola ní Ogbomosho lòun ti ń sèrànwọ́ àti ìgbaniníyànjú fún àwọn ènìyàn, èyi ni bí ó se di gbajúgbajà.

Image copyright @ShinaPeller
Àkọlé àwòrán Àworan Shina Peller

Shina Peller tún mẹ́nu ba ọrọ̀ ajé orílẹ̀èdè Nàìjíríà, ó tẹnu mọ ọ wí pé ìgbafẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní tó le è mú ọrọ̀ ajé Nàìjíríà gbòòrò síi.

Ó rọ ìjọba láti yé se ojú ayé lórí ọ̀rọ̀ à ń sọ ọrọ̀ ajé di ọ̀pọ̀ yanturu sùgbọ́n kí wọ́n dojú kọ ọ́ bó ti tọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌṣẹlẹ iyinbon APC Ekiti : Ki gaan lo ṣẹlẹ?