Ohun tó sọ Okorocha di olóròróó ọ̀sán gangan

Gomina Ipinle Imo, Okorocha Image copyright IGBERE TV
Àkọlé àwòrán Àwọn mìíràn ní bóyá Rochas Okorocha ti sọ ara rẹ̀ di wòlíì ni

Gómínà ìpínlẹ̀ Imo, Rochas Okorocha, di ẹni tí ń ṣe ìfàmi-òróró-yàn fún àwọn ará ijọ nínú ilé ijọ́sìn?

Ìbéèè yìí ló gba ayé kan nígba tí àwọn fọ́to ṣàfihàn rẹ ninu ìsìn tó wáyé nílé ìjọsìn tó wà nínú ilé ijọba ìpínlẹ̀ náà ní Owerri l'ọ́jọ́ Aiku.

Awọn kan gbà pé agbára òṣèlú ni

Àwọn mìíràn ní bóyá ó ti sọ ara rẹ̀ di wòlíì ni o.

Sùgbọ́n nígbà tí BBC kan sí gómínà náà láti mọ ǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀, olùrànlọ́wọ́ pàtàki rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìfitónilétí, Ebere Nzewuji, ni kò rí bẹ́ẹ̀.

Ó ṣalayé pé, wón ní kí ọmọ ìjọ kọọkan fi oróró sí iwájú orí ẹni tí ó wà ní sàkání rẹ̀ ní.

Sùgbọ́n àwọn ayàwòrán ni wọ́n ya gómínà náà nígba tó ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sí gbẹ́e síta tí ó fi dà bí ẹni pé ó ń ṣe bí wòlíì.