June 12: Awọn ọmọ Abiọla sọrọ lori idanilọla fun MKO

Àkọlé fídíò,

‘Mo fẹ́ mọ ẹni tó jáwé olúborí nínú ìdìbò June 1993’ - Abdulmumini Abiola

Àwọn ọmọ Abiọla fi ìdùnnú hàn sí ìkéde Aarẹ Buhari lórí June 12

Bí àarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari, ṣe kede ọjọ kejila, oṣu kẹfa gẹgẹ bii ayajọ tuntun fun iṣejọba awa-ara-wa l'awọn eeyan ti kọ oniruuru iha sii

Yorùbá bọ wọn ni onikangun-n-kangun, aṣọ to ba kangun si eegun ni wọn n pe ni jẹ̀pẹ̀, awọn ọmọ oloogbe MKO Abiola fimoore hàn fun ikede aarẹ Buhari yii.

Awọn naa ni gbogbo agbaye ri gẹgẹ bii àmì idanimọ fun baba wọn ati opo ijijagbara to waye nipasẹ idibo ọjọ kejila, oṣu kẹfa ọdun 1993.

Oríṣun àwòrán, @wura_abiola

Àkọlé àwòrán,

Lẹ́yìn ogún ọdún tí ó jáde láyé, ìjọba àpapọ̀ ṣe ẹ̀yẹ fún olóògbé MKO Abíọ́lá

Ọdun 1993 ni ijọba fagile idibo ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Hafsat Abiola-Costello

Hafsat Abiola-Costello, ọmọ ti Alhaja Kudirat Abiola, ọkan lara awọn to ba ijijagbara fun idapada ijọba alagbada lẹyin iwọgile esi idibo June 12 lọ, bi fun Oloye Abiola ni idunnu nla gbaa ni ikede ọhun jẹ fun oun ati gbogbo ẹbi MKO Abiọla.

Oríṣun àwòrán, Paul Morigi

Àkọlé àwòrán,

Inú mi dùn gidi pé ijóba pọ́n baba mi lé lásìkò yìí

"Ko si ọrọ kan pato to lee sọ ọkan imoore mi ati ayọ to n bẹ ninu mi. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to mu ki o ṣoju mi"

Hafsat Abiola-Costello ni oun ti n reti igbesẹ̀ naa ti pẹ́, ki o to waye bayii.

"Ireti mi ni pe nigba ti ologun da ijọba pada falagbada, yoo ṣe bẹẹ ni ọjọ kejila, oṣu kẹfa, eleyii ti yoo saami aṣepari igbesẹ to bẹrẹ pẹlu ala rere ti awọn kan danu ṣugbọn asan ni ireti mi, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un ni wọn fi si nigba naa.

Mo ro pe ẹni akọkọ to janfanii rẹ yoo tilẹ ni ki orilẹ-ede yii dakẹ iranti iṣẹju kan fun un sibẹ, asan ni ireti mi jasi."

Abdulmumini Abiola

Lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari kẹdẹ June 12 gẹgẹ bii 'Ayajọ Ọjọ Isejọba tiwantiwa', ọmọ M.K.O. Abiola, Abdulmumini Abiola, ni inu oun dun lọpọlọpọ.

Abiola to fi ìdìnnú rẹ hàn sikede Aarẹ Buhari naa ni pe ẹbun Ramadan pataki ni eyi jẹ fun oun.

Bakan naa lo ke si ijọba lati se ofintoto ẹni tó jáwé olúborí nínú ìdìbò June 1993 lati le mu inu awọn mọlẹbi awọn ti ẹmi wọn lọ si idibo naa lodun ọhun.

Wura Abiola

Wura Abiola ni tirẹ ni ọjọ ayọ leyi lati pe ara oun ni ọmọ Naijiria tọkantọkan.

Ninu ọkan-o-jọkan atẹjade to fi si oju opo twitter rẹ, Wura Abiola ni idunnu nla ni ọrs naa jẹ fun oun.

"Baba mi ọwọn Baṣọrun Moshood Kashimawo Olawale Abiola GCFR. Inu mi dun gidigidi pe lẹyin o rẹyin mo lee kọ ọrọ yii lẹyin ogun ọdun. Mo dupẹ lọwọ yin o Aarẹ Buhari."

Ni ọjọru ni aarẹ Buhari kede ọjọ kejila, oṣu kẹfa, gẹgẹ bii ọjọ ti orilẹ-ede Naijiria yoo maa ṣe ayajọ iṣejọba tiwantiwa.

Bakan naa ni aarẹ kede oye to ga julọ lorilẹede Naijiria, GCFR fun oloogbe Oloye MKO Abiọla.

Aarẹ Buhari tun fi oye to ga julọ ṣekeji, GCON da ogbontagi ajafẹtọ ọmọ-niyan to ti doloogbe, Amofin agba Gani Fawehinmi, ati Alhaji Baba Gana Kingibe naa lola