June 12: Ribadu ni Fawẹhinmi ni akin tí a gbọ́dọ̀ yẹ́ sí

Gani Fawẹinmi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gani Fawẹinmi kó ipa to kúrò ni kèrémí fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ iṣejọba alágbádá ni Naijiria

Nuhu Ribadu ti kan sárá si bi aarẹ Muhammadu Buhari ṣe da ogbontagi ajafẹtọ araalu ni, Oloogbe Gani Fawehinmi lọla.

Nuhu Ribadu ti figba kan jẹ alaga ajọ to n gbogunti iwa ibajẹ gbogbo to rọ mọ iṣuna lorilẹ-ede Naijiria, EFCC.

Ni ọjọru ni Aarẹ Muhammadu Buhari kede ami ẹyẹ to ga julọ ṣekeji lorilẹ-ede Naijiria, GCON fun Oloogbe amofin agba Gani Fawehinmi, SAN.

Ninu ọrọ rẹ, Mallam Nuhu Ribadu ṣe apejuwe Gani gẹgẹ bi 'ọkan ṣoṣo araba'ajafẹtọ to fi gbogbo aye rẹ jin fun orilẹ-ede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Lai simi ati lai kaarẹ ni Gani ja fun ja fun ẹtọ ọmọniyan ati ibọwọ fun ofin. Akinkanju tootọ ni Gani ti o si yẹ ki a maa ṣe afẹri rẹ nigba gbogbo."

Nuhu Ribadu ni yatọ si ọrọ iṣejọba tiwantiwa ajọyọ nla ni igbesẹ naa jẹ fun ijijagbara ati ifaraẹnijin fun igbayegbadun gbogbo eniyan lorilẹede Naijiria.