Afẹ́nifẹ́re: Buhari rò pé òun gbọń lójú ara òun ni pẹ̀lú ìkéde yìí

Àkọlé fídíò,

Afẹ́nifẹ́re: Ọgbọ́n ìbò ni Buhari ń dá

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣapejuwe ikede Aarẹ Buhari gẹgẹ bii ọgbọn alumọkọrọyii lati fi ṣi oju awọn ọmọ Naijiria kuro ninu gbogbo aṣiṣe rẹ

Aarẹ Buhari kede ọjọ kejila, oṣu kẹfa gẹgẹ bii ayajọ tuntun fun iṣejọba tiwantiwa lorilẹ-ede Naijiria.

Bakna naa lo foye to ga julọ da oloogbe MKO Abiọla lọla (GCFR) pẹlu oloogbe Gani Fawẹinmi (GCON).

Ẹgbẹ Afẹnifẹ ni, bi o tilẹ jẹ pe awọn faramọ ikede naa, inu awọn si dun si, sibẹ ohun ti ọjọ kejila, oṣu kẹfa duro fun ninu itan orilẹ-ede Naijiria ju kikede ọjọ naa gẹgẹ bii ayajọ ijọba tiwantiwa nikan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

June 12: Lai Mohammed ni Buhari ti wo ọgbẹ́ June 12 sàn

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọmọwe Yinka odumakin ni ohun ti June 12 duro fun ni iṣọkan orilẹede Naijiria lai si idẹyẹsi ẹsin, ede tabi ẹya eleyi ti wọn ni o ti sọnu lorilẹede Naijiria lọwọ yii.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun sọ pe, idibo sipo gomina nipinlẹ Ekiti ni yoo sọ boya ootọ inu ni Aarẹ Buhari fi ṣe ikede naa ati idanilọla to ṣe fun Oloogbe MKO Abiọla.