Muhammed Fawẹ̀hinmi: Bàbà mi yóò dunú níbi tó bá wà báyìí

Àkọlé fídíò,

Muhammed Fawẹ̀hinmi: Bàbà mi yóò dunú níbi tó bá wà báyìí

"Kání Gani wa laye ni, yoo tẹwọ gba ami idanilọla yii"

Akọbi oloogbe amofin agba Gani Fawẹhinmi, (SAN) Ọgbẹni Mohammed Fawẹhinmi, sọ fun BBC Yoruba pe oyẹ yii ko ba dun mọ baba oun ninu pupọ ka ni ko tii filẹ bora bi aṣọ ni.

Oye GCON ni oye keji to tobi julọ ni Naijiria.

Mohammed ni ohun idunnu patapata lo jẹ fun ẹbi oloogbe Gani Fawẹhinmi pe awọn ohun to jẹ ẹdun ọkan fun ajafẹtọ naa tẹlẹ, ti ó ja fun titi di ọjọ iku ni Aarẹ Buhari fọwọ si bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àrólé Gani Fawẹhinmi, Mohammed ní inú bàbà òun yóò dùn lórí àmì ìdánilọ́lá GCON

O ni ohun to jinna si ootọ ni ọrọ ti awọn kan n sọ pe ka ni Amofin agba, Gani fawẹhinmi wa loke erupẹ ni, ko ni gba ami idanilọla naa, paapaa bi o ti jẹ pe o ti figbakan ri kọ awọn irufẹ ami idanilọla bẹẹ nigba ti o wa laye.

Muhammed fawẹhinmi ni Gani Fawẹhinmi yoo gba ami idanilọla naa, bi o tilẹ jẹ pe, o lee gba tan, ko kọ oju oro si Buhari lori bi nkan ṣe dagun lorilẹ-ede Naijiria bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: