Bàálù Ọsinbajo: Kété tó gbéra tán ló ń yọ̀ èèfín

Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo
Àkọlé àwòrán,

Baalu kekere naa lo ni isoro ranpẹ laarin isẹju perete to gbera nilẹ.

Ọlọrun kó Naijiria yọ lọwọ ijamba ojiji ti ko bà fa ọ̀fọ̀ l'Ọjọbọ

Ijamba ojiji kan ni Ọlọrun koore rẹ ni orilẹ-ede Naijiria nigba ti baalu kekere to gbe igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo, deede bà silẹ pada ni kete to gbera tan.

Bi wọn ṣe gbéra ni ileẹkọ awọn osisẹ asọbode to wa ni Gwagwalada nilu Abuja niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

A gbọ pe baalu kekere naa lo ni isoro ranpẹ laarin isẹju perete to gbera nilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo lo bawọn peju si ibi ayẹyẹ ikẹkọjade fawọn lọga-lọga osisẹ asọbode.

Ni kete ti ayẹyẹ naa wa sopin ti igbakeji aarẹ si wọ baalu alawọ tinu ẹyin (YELLOW) ati olomi aro (BLUE) naa, to si gbera, ni ko lee fo kọja awọn igi to wa nile ẹkọ̀ naa, to si tun n yọ eefin.

Ni kete ti isẹlẹ́ yii waye, ti ori si ko Yẹmi Ọsinbajo yọ, lo ba wọ inu ọ̀kọ lati kuro nibẹ.