Ghana f'ofin de gbogbo ọ̀rọ̀ eré bọ́ọ̀lù torí rìbá lásìko yìí

Owo riba ti wọn n fun ẹ́nikan
Àkọlé àwòrán,

Ogunlọ́gọ̀ àwọn adarí ni àwọn akọ̀róyin fún ní owó láti ṣe màgòmágó ṣùgbọ́n wọ́n ya àwòrán wón laí mọ̀.

Lẹ́yin ìwádìí iléesẹ́ BBC pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Anas Arameyaw Anas, akọ̀ròyìn ọmọ Ghana kan, nijọba Ghana ṣe ìkéde tuntun yìí

Eyi tumọ si pe yoo pa idije Liigi Abẹ́lé àti ti àwọn agbbọọlu agba lára.

Wọn gbé fídíò ìwádìí ọhun jáde lórí bí àwọn adarí eré bọ́ọ̀lù ṣe ń gba rìbá láti ṣe màgàmágó.

Ìjọba orílẹ̀-èdè náà ati awọn aṣofin rẹ̀ ti ní kí ọlọ́pàá bẹ́rẹ̀ iṣẹ́ láti ṣe ìwádìí àwọn èèyàn tí ọ̀rọ̀ náà ta bá kiakia.

Nínú fídíò náà tí wọn pè ní Number 12, tí wọ́n ṣe àfihàn rẹ̀ ní Ọjọ́bọ, ni a ti gbọ́ pé, ogunlọ́gọ̀ àwọn adarí eré bọ́ọ̀lù ni àwọn akọ̀róyin fún ní owó, láti ṣe màgòmágó ṣùgbọ́n wọ́n ya àwòrán wón laí mọ̀.

Anas tí ó jẹ́ akọ̀ròyin ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó máa ń da agọ̀ bojú kí wọn má bàá lé rí ojú rẹ̀, sọ pé, màgòmágó àti rìba ti ba ere bọ́ọ̀lù jẹ́ ní Ghana.

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀gá àgbà fún àjọ eleré bọ́ọ̀lù ni Ghana (GFA) Kwesi Nyantakyi gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà márunléọgọ́ta dọ́là gẹ́gẹ́bíi rìbá.

Èyí tó ga jù nibẹ ni ti ọ̀gá agba àjọ tí ó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù ni Ghana (GFA), Kwesi Nyantakyi, tí ó gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà márunléọgọ́ta dọ́là gẹ́gẹ́ bíi rìbá.

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Ghana ti ní Nyantakyi àti àwọn mìíràn tí wọn gba rìbá naa ni yóò wọ wàhálà.

Àkọlé àwòrán,

Fidiò náà ṣe àfihàn Kwesi Nyantakyi bí ó ṣe gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà márunléọgọ́ta dọ́là gẹ́gẹ́bíi rìbá

Àtẹ̀jáde orílẹ̀-èdè Ghana rèé lórí ọ̀rọ̀ náà:

Oríṣun àwòrán, GHANA PRESIDENCY

Àkọlé fídíò,

Ẹtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀