Awọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Anambra ti ń jànfàni #5000

Iya to joko
Àkọlé àwòrán Ìjọba Nàìjíríà ń san ẹgbẹ̀rún márùn-ún márùn-ún fún awọn ènìyàn to tálákà jùlọ ní orílẹ̀-èdè yìí

Láìpẹ́ yìí ní ìjọba àpapọ̀ kéde láti máà san ẹgbẹ̀rún márùn-ún gba fún àwọn tálaákà lórìlẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Owó yìí ni yóò jẹ́ atọ́nà sáájú pínpín owó Abacha ti wọ́n rí gbà fún àwọn ènìyàn.

Awọn owó ti wọn jí kó tó kù
Àwọn owó tí wọn dá padà
 • $2-5bn
  1998
  Ìgbéléwọ̀n àjọ Transparency international fi hàn pé láàárín 2bílìọ̀nù - 5 bílìọ̀nù dọ́là ni owó tí ọ̀gágun Sani Abacha jí kó
 • $750m
  1998
  Ọ̀gágun Abdulsalam Abubakar, tó jẹ́ olori orílẹ̀-èdè nígbà náà rí àádọ́talélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rin(750) dọ́là owó gbà lọ́wọ́ àwọn ebí Abacha ní onírúúrú owó ilẹ̀ òkèrè
 • $64m
  2000
  Orílẹ̀-èdè Switzerland dá 64 mílìọ̀nù dọ́là pada
 • $1.2bn
  2002
  Ààrẹ Obasanjọ bá ìdílé Abacha dìí kí ó ba lè rí 1.2 biliọ̀nù gbà padà
 • $160m
  2003
  Wọn gba160 míliọnù dọ́là padà láti Jersey, British Isles. ìjọba Nàìjíríà sọ pe àwọn rí 149 milìọ̀nù dọ́là
 • $88m
  2003
  88 milìọ̀nù dọ́la ni ìjọba Switzerland dá padà
 • $461m
  2005
  ọ̀kànlélọ́gọ́talénírinwó (461.3) milíọ̀nù dọ́là ni ìjọba Switzerland dá padà. Mínísítà fún ètò ìsúná nígbà náà Ngozi Okonjo Iweala tó tún jẹ ààrẹ Banki àgbáyé sọ pé 458 mílíọ́nù dọ́làní àwọn rí nínú ilé ìfowópamọ́ náà ni wọn ti dá padà.
 • $44m
  2006
  mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì dọ́là tí wọ́n dá padà láti orílẹ̀-èdè Switzerland
 • $227m
  2014
  ẹtàdínlọ́gọ́riinlénígba (227) mílíọ̀nù dọ́là ni mínísítà ètò ìsúná sọ pé àwọn Liechtenstein
 • $320m
  2017
  Oòkòólélọ́dúrún mílíọ̀nù dọ́là ni ìjọba Switzerland dá padà

Orísun

Transparency International, ìjọba Nàìjíríà, Banki àgbáyé, Agbejọ́rò àgbà, report Jersey

Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti wa dí òòtọ́ọ́ báyìí bí ètò náà ṣe ti bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹwu, àwọn ènìyàn kan ní abúlé Ifitedunu, ni ìjọba ìbílẹ̀ Dunukofia nípinlẹ̀ Anambra ló jẹ́ri si ọ̀rọ̀ yìí nígbà ti wọn ń bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìjọba Nàìjíríà ń san ẹgbẹ̀rún márùn-ún márùn-ún fún awọn ènìyàn to tálákà jùlọ ní orílẹ̀-èdè yìí.

Àjọ̀ tó ń rí sí pínpín owó nílè ìjọba àpapọ ló ń ri kí ìlú náà, wọn ni àwọn ṣe ìforúkọ sílẹ̀ nítorí pé ìpele àkọ́kọ́ kò kan àwọn míràn.

Àkọlé àwòrán Abacha Loot: Awọn ìpínlẹ̀ Anambra ti ń jànfàni #5000

Awọn to gba owó náà sàlàyé fún BBC Pidgin pé àwọn ti gba owó náà bí ẹ̀mẹ́fà báyìí àti pé oṣooṣù ni wọn máà ń fun àwọn ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá.

Wọn ni ẹgbẹ́run márùn ọ̀hún kò tó ǹkankan sùgbọ́n ogún ẹgbẹrun náírà yóò wúlò fun gbogbo ǹkan ti àwọn bá fẹ́ fi ṣe.

Bó tilè jẹ́ pe àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò PDP ti sọ pé àrékereke òṣèlú lásán ni ọ̀rọ̀ owó náà.

Àkọlé àwòrán Kìí ṣe gbogbo ìpínll ni owó náà ti de báyìí

Kìí ṣe gbogbo ìpínlẹ ni owó náà ti de báyìí sùgbọn àwọn àjọ to ń ri sí àmúludùn àti ààbo àrá-ìlú (NASSCO) ti ń lọ káàkiri láti gba orúkọ sílẹ̀ nígbà ti àjọ tó ń ri sí pínpín owó náà yóò máa san owó.

Àkọlé àwòrán Ìjọba Nàìjíríà ń san ẹgbẹ̀rún márùn-ún márùn-ún fú awọn ènìyàn to tálákà jùlọ ní orílẹ̀-èdè yìí.

Èto ọ̀hún jẹ́ ti Banki àgbáyé láti ran àwọn orilẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí ìpín àwọn aláìní ènìyàn baà lè dínkù, sùgbọn wọn ni àwọn ń fi ojú sí owó náà láti rii dájú pé magòmágó ò wáyé.

Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ọdún 20 tí Abacha kú

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ènìyàn kò gba ọ̀rọ tí Dokita íjọba sọ pé àìsàn ọkàn ló pa á

Ogun ọdun ti kọja lẹyin ti Ọgagun Sani Abacha to jẹ adari orilẹ-ede Naijiria lọdun 1993 si 1998 ku iku ojiji.

Sani Abacha to jẹ ọmọ bibi ilu Kanuri lati ipinlẹ Borno. O lọ si ile iwe ọlogun ti Kaduna ko to gba oye ọgagun lọdun 1963.

Titi di oni to jẹ ayajọ ọjọ ti oloogbe naa papoda, ọ̀pọ̀ awọn ọmọ Naijiria ko sọ nkan rere nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌrọ ìfẹ́: Tunrayọ Adeoye kú lọ́sẹ̀ karun ti a sin ọkọ rẹ̀

Awọn miran sọ pe ọwọ lile ni Abacha fi se ijọba nigba aye rẹ, ti ọpọlọpọ ajafẹtọ ọmọ eniyan sọ pe o ru ofin to de ihuwa si ara ilu.

Awọn miran fẹsun kan an pe, o lu ọpọlọpọ owo ilu ni ponpo nigba aye rẹ, ati pe awọn eniyan gbagbọ pe obinrin lo se iku pa a.

Amọ, Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ati awọn ọmọ Naijiria miran gbagbọ pe asiko rẹ tu eniyan lara nitori ipese ohun amayedẹrun bii ina ijọba, ọna to gbooro, ẹkọ ọfẹ ati eto ilera fun awọn eniyan.