Koko iroyin: Lai Mohammed fèsì sí ọrọ Obasanjo, Ìjọ́ba ìpínlẹ̀ Ògùn kéde ìsinmi ní June 12

Èyí ni àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn tí tòní

Lai Mohammed: Ọbasanjọ, bí ìwo bá ṣé réré, Ara kì yóò yà ọ?

+

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọbasanjọ ti ṣe nnkan ìtùfù sẹyin lo ṣe n kíyèsí ẹninkule rẹ̀

Ẹní jẹ fufu lára n fu lọ̀rọ̀ Ọbasanjọ.

Èsì ọrọ ree láti ọdọ ìjọba Buhari sí Obasanjo to so pe Buhari n pète láti ka ẹsùn sí òun lọrùn lasiko yii.

Mínísítà fún ètò ìròyìn,Alhaji Lai Muhammed, lo fèsì naa pada pé ''àhesọ ọ̀rọ̀ ni Ọbasanjọ n sọ, àti pé ìjọba Buhari kò ráàyè a n dìràn mọ́ni lẹ́sẹ̀''

Ọrọ náà jẹyọ nínú aàtẹ̀jáde kàn tó fí ṣọwọ́ s'awọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ẹtì nílùú Èkó. Ẹ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ níbí

June 12: Ògùn, Ọ̀yọ́ kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, http://ogunstate.gov.ng

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù Kẹfà, gkgẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.

Èyí jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé fún ìjọba ìpínlẹ̀ nàá, Taiwo Adeoluwa fọwọ́ sí.

Nínú àtẹ̀jáde nàá tó tẹ ìwé ìròyìn Punch lọ́wọ́, wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa. E ka ekunrere re ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

'Bóo rántí ikú Gáà kóo ṣòótọ́ ni ọ̀rọ̀ Abacha'

Àkọlé fídíò,

'Ọpọ̀ ẹ̀mí èèyàn ló bọ́ lọ́wọ́ Abacha láàrín 1993 sí 1998'