Ọlọ́pàá: Agúnbẹ náà kò ju ọ̀bẹ sílẹ̀ la fi yìnbọn páá

Ọbẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọlọpaa ni Agúnbẹ náà kò ju ọ̀bẹ sílẹ̀ ni wọn se fi yìnbọn páá

Eeyan mẹta lo padanu ẹmi wọn lẹyin ikọlu mọsalaasi miran l'orilẹede South Africa.

Ikọlu naa ṣẹlẹ ni deedee agogo mẹta oru nigbati awọn musulumi n mura fun adura owurọ ni Malmesbury lagbegbe ilu Cape Town.

Iroyin sọ di mimọ pe, ọkunrin kan lo wọ mosalaasi, to si beere ọna, ko to f'ọbẹ gun eeyan meji pa lojiji ti eeyan mẹta si f'arapa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Gbolahan Kabiawu: Fífi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ dára fún ẹ̀yà ara

Awọn agbofinro fidi rẹ mulẹ pe okunrin naa, to to ẹni ọgbọn ọdun kọ lati fi ọbẹ to mu dani silẹ, to si doju kọ ọlọpaa to wa nibẹ ki ọlọpaa naa to yinbọn paa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìkọlù mọ́sáláásí ní ìlú Cape Town mú ẹ̀mí okùnrin tó gún èèyàn méjì pa náà lọ

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn se apejuwe ọbẹ ti okunrin naa lo bi ọbẹ Rambo.

Ikọlu yii ṣẹlẹ lẹyin osu kan ti iru rẹ ṣẹlẹ ni mọsalaasi kan ni apa ariwa ilu Durban, l'orilẹede South Africa.