Keyamo: N kò nígbàgbọ́ nínú àwọn tó ń sisẹ́ pẹ̀lú Buhari

Festus Keyamo

Oríṣun àwòrán, @fkeyamo

Àkọlé àwòrán,

Keyamo ni kìí ṣe ààrẹ ní yóò kó orúkọ àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ jọ, àwọn òsìsẹ́ ni

Olùdarí féka ètò ìbánísọ̀rọ̀ lábẹ àjọ ìpolongo ìbò fún Muhammadu Buhari, Festus Keyamo ( SAN) sọ pé, ààrẹ Muhammadu Buhari nìkan ní òún le fọwọ́sọ̀yà fún, gẹ́gẹ́ bí olóòtọ́ọ́ nínú gbogbo àwọn tó ń báa ṣiṣẹ́.

Keyamo sọ̀rọ̀ ọ̀hún nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò kan ní ìlú Abuja.

Keyamo sọ̀rọ̀ yìí ní ìdáhùn sí ẹ́sùn kan pé, ìjọba Buhari fárí apá kan, dá apá kan si, àti pé, àwọn òsìsẹ́ ń gba ọ̀nà ẹ̀yìn wọ Bánkì orilẹ̀-èdè Nàìjíríà (CBN).

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ní "mo ránti pé nígbà kan, àwọn ènìyàn ń pariwo pé wọ́n fún àwọn ènìyàn ẹkùn ibì kan níṣẹ ju àwọn ẹkùn míràn lọ, sùgbọn ọ̀pọ̀ àwọn ǹkan wọ̀nyìí tí ó bá dé détigbọ́ ààrẹ, Buhari kò lè káwọ́ gbera lórí rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, @AsoRock

Àkọlé àwòrán,

Kìí ṣe ààrẹ Buhari ní yóò kó orúkọ àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ jọ, àwọn òsìsẹ́ ni, ẹnikẹ́ni kò sì lée gba ẹ̀rí wọn jẹ.

Kìí ṣe ààrẹ ní yóò kó orúkọ àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ jọ, àwọn òsìsẹ́ ni, ẹnikẹ́ni kò sì lée gba ẹ̀rí wọn jẹ.

Nígbà ti ọ̀rọ̀ ọ̀un jẹyọ, ààrẹ Buhari dáwọ́ ìgbanisísẹ́ ọ̀hún dúro

Keyamo bẹ́nu àtẹ́ lu àwọn tí wọn sọ pé, ààrẹ ń fárí apa kan, dá apákan sí láti máa yan àwón èèyàn apá Aréwa nìkan sí ipò to ga jù.

Keyamo wa rọ àwọn Nàìjíríà láti mase fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n maa pa làpálàpá kiri.