2000 ọ̀dọ́ ìpínlẹ̀ Oṣun jàǹfàní ìkọ́ṣẹ́ lọwọ́ ìjọba àpapọ̀

Awọn ọdọ to janfani ẹkọṣẹ naa Image copyright Bosẹ Sodiq
Àkọlé àwòrán Iṣẹ́ ọnà, àsè gbígbà, ilé ṣíṣe lọ́ṣọ́ àti kẹ́míkà ṣíṣe kún ara iṣẹ́ ọwọ tí wọ́n kọ́ àwọn ọ̀dọ́ náà

Gẹgẹ bii ara eto lati le airiṣẹ wọlẹ lorilẹ-ede Naijiria, ijọba apapọ ti ṣeto ikọṣẹ ọwọ fun ẹgbẹrun meji awọn ọdọ nipinlẹ Ọṣun.

Awọn ẹgbẹrun meji naa ni wọn ṣa kaakiri awọn ijọba ibilẹ mẹwaa lẹkun idibo aringbungbun Ọṣun ati ijọba ibilẹ Ede South nipinlẹ naa.

Awọn alakoso eto ọhun, Liberty Olawale Badmus ati Ọmọwe Saka Ominiwe, ni afojusun eto ikọṣẹ ọfẹ naa ni lati fun awọn ọdọ ni anfani igbagbọ ninu ara wọn bi o ti ṣe wa lawọn orilẹ-ede kaakiri agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O tẹnumọ pataki ṣiṣamulo awọn ẹkọ ti wọn kọ lati mu ayipada rere ba ara wọn ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

Ọmọwe Saka Ominiwe ni bi igbesẹ naa ba n tẹsiwaju, yoo mu iṣoro airiṣẹ di ohun igbagbe lorilẹ-ede Naijiria.

Wọn ni eto ọhun ti kọkọ waye ni ipinlẹ Eko lati gbe igbesẹ fun riro awọn ọdọ lagbara lati da duro pẹlu bi iṣẹ ọba ati aladani ṣe di wahala nitori bi ọrọ aje ṣe ri.

Gbogbo awọn ọdọ naa ni wọn kọ ni ẹkọ iṣẹ ọna, ṣiṣe ile lọṣọ, fọtọ yiya ati ṣiṣe eroja kẹmika ati bẹẹbẹẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRussia 2018:Super Eagles ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdíje tó kọjá