Ìsẹ̀lẹ̀ Èkó: Àwòrán bí èèyàn mẹ́ta se bá ìjàmbá lọ

Ajọ to n risi ìsẹ̀lẹ̀ pajawiri ni ipinlẹ Eko, Lasema, to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, fi kun un p, eniyan mẹta naa ku loju ẹsẹ, ti ọpọ si farapa.

Afara Ojuẹlẹgba ni ilu Eko
Àkọlé àwòrán,

Awọn igi to da wo labẹ afara naa

Ọkọ̀ akérò kan tí igi náà wó lù mọ́lẹ̀ ló rún jégé-jégé.

Àkọlé àwòrán,

Ìjàmbá kò nílé, àfi kí Ọba òkè máa kó wa yọ

Èrò kò gbẹsẹ̀ ní ibití ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Àkọlé àwòrán,

Ń se ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń bèèrè pé sé kò yẹ ká leè máa dènà irúfẹ́ ìjàmbá bíi èyí?

Kò sí ibi tó kù mọ́ lára ọ̀kọ̀ tí igi wó lù yìí

Àkọlé àwòrán,

Àwọn agbófinró ti ta okùn dí agbègbè ibití ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Àlààfíà ti ń padà sí àdúgbò Ojúẹlẹ́gba, tí àwọn òsìsẹ́ ìjọba sì ti ń tún àyíká ibití ìsẹ̀ll náà ti wáyé se

Àkọlé àwòrán,

Àwọn òsìsẹ́ tó ń gbá ilẹ̀ kò jáfara láti se ìtọ̀jú àyíká náà

Kátà-kárà ti bẹ̀rẹ̀ padà ní agbègbè tí ìjàmbá náà ti wáyé.

Àkọlé àwòrán,

Ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò ní Ojuẹlẹgba ni ilu Eko

Gbàgede òkè àti ìsàlẹ̀ ibití ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá náà ti wáyé

Àkọlé àwòrán,

Isẹ́ ńla ló wà níwájú àwọn òsílẹ̀ tó ń gbálẹ̀ ní Ojúẹlẹ́gba

Àwòrán ọ̀kọ̀ tó ní ìjàmbá gbẹnu tán ní Ojúẹlẹ́gba.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn èrò ya ẹnu lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà, wọn kò leè pádé mọ́

Haa, irú kín ni èyí ni ọ̀pọ̀ èèyàn n sọ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn èèyàn tó ń ya ẹnu, lórí ìsẹ̀ll náà

Ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá tó mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́ta lọ nigba ti igi nla rebọ lati ori ọkọ agbegi to n sọkalẹ lori afara Ojuẹlẹgba ni ilu Eko gba ẹ̀nu tán.

Oríṣun àwòrán, Alamy

Àkọlé àwòrán,

Bí èèyàn bá jẹ orí ahun. yóò kẹ́dùn ní Ojúẹlẹ́gba