Fẹmi Adebayọ: Òsèré tíátà Yorùbá kò leè gba owó ju òsèré olóyìnbó lọ

Femi Adebayo

Ọmọ to ba mọ́ iya abi baba rẹ loju osi ni yoo ta ọmọ naa pa ni Yoruba maa n sọ. Eyi to ba tiẹ wa na obi rẹ, o ti jẹ eewọ. Sugbọn eyi ko rii bẹẹ rara taa ba n sọrọ awọn osere ori itage.

Ilumọọka osere tiata kan, Fẹmi Adebayọ ti ni ohun to buru julọ ti oun tii se ninu ere ori itage ni ere kan ti wọn ti ni ki oun gba baba oun, Adebayọ Salami, ti gbogbo eeyan mọ si Ọga Bello leti.

Fẹmi ni ti kii ba se ere, kin ni oun ko ba jẹ yo, debi ti oun yoo maa gba baba oun leti pẹlu afikun pe gẹgẹ bii osere tiata to dantọ, ojuse ti wọn gbe le oun lọwọ ninu ere ni eyi, oun si gbọdọ see ni.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:

Àkọlé fídíò,

Femi Adebayo: Ẹyin ọ̀dọ́, ẹ káàbọ̀ ságbo ilé Tíátà

Nigba to n ba akọroyin Punch sọrọ, Fẹmi Adebayọ ni, oun ko ri baba oun bii baba oun rara to ba di ẹnu isẹ tiata, o ti di akẹẹgbẹ oun ti awọn dijọ n sisẹ, tawọn si gbọdọ se ojuse awọn daadaa.

O fikun pe baba oun lo kọ oun ni isẹ tiata, ọga oun si lo tun jẹ, to si ti kọ oun pe nigb-kuugba ti oun ba pade awọn agba osere lẹnu isẹ, oun ko gbọdọ bẹru rara .

Fẹmi ko sai fi kun pe "ni kete ti oludari ere ni o to, ni mo yara dọbalẹ lati tọrọ aforijin lọwọ mi pe ko ma binu pe mo fọ oun leti."

Fẹmi Adebayọ tun fi kun pe ko seese ki osere tiata lede Yoruba maa gba owo ju awọn akẹ́ẹgbẹ́ rẹ to n sọ oyinbo lọ.

O ni idi ni pe awọn ẹya Yoruba nikan lo n ra fiimu lede Yoruba, nigba ti fiimu oloyinbo jẹ itẹwọgba kari aye.

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Àkọlé àwòrán,

Ilé náà tó kùn ní àwọ̀ búlùù ojú sánmọ̀ àti ti ọtí wáìnì ló ní gbàgede ìgbafẹ́ ní òkè àti ìsàlẹ̀

Gbajú-gbajà òsèré tíátà ni óbìnrin, Mercy Aigbe ti ra ilé alájà kan tó jẹ́ àwòsí-fìlá.

Ilé náà, tó jẹ́ àwọ̀ búlùù ti ojú sánmọ̀ àti ti ọtí wáìnì, ló ní gbàgede ìgbafẹ́ ní òkè àti ìsàlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló tún ní ilẹ̀ tó tẹ́jú nínú àgbàlá rẹ̀ láti yan fanda,

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mercy Aigbe, tó ti se eré tíàtà ní èdè Yorùbá àti òyìnbó, ló kéde pé òun ti di ìyá onílé tuntun, ní ojú òpó Twitter rẹ̀ ní ọjọ́ ìsẹ́gun.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Aigbe kò sọ agbègbè tí ilé náà wà, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọ̀n akẹgbẹ́ rẹ̀ ló ti ń ki kú oríire ní ojú òpó Twitter wọn.

Mide Martins, tóun náà jẹ́ òsèré tíátà míì, ní ojú òpó twitter rẹ̀@mydemartins ní, inú òun dùn pé Mercy gbé ohun rere se, tó sì ń bèèrè pé ìgbà wo ni àwọn yóò sí ilé náà.

Nigba to n jẹ́ri lori ile naa, Mercy Aigbe ni ọ̀kan lara awọn eeyan oun kan, tyo pe orukọ rẹ ni Luminee, lo fi akara oyinbo ti wọn mọ bii ile alaja kan ta oun lọrẹ lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun oun ti oun se ni ibẹrẹ̀ ọdun tii.

Mercy ni Luminee gba adura fun oun pe ki ọdun yii to pari, oun naa yoo ni ile ti ara oun, ti oun si fesi pada pe ko fi oun silẹ, nitori ile ti oun n kọ lọwọ, oun ko tii pari rẹ.

O ni Luminee ni oun ko sọ nipa ile naa, amọoun n sọ̀ nipa ile to rwea, ti oun yoo ra si agbegbe to jẹ oju ni gbese ni ilu Eko, ti oun si jaa niyan pe nibo ni oun ti fẹ́ ri owo banta-banta lati iru ile bẹẹ.

Luminee wa sọ fun oun pe ki oun mase se aniyan lori rẹ rara nitori Ọlọrun yoo bu kun oun, ti yoo si ro oun ni agbara.

Àkọlé àwòrán,

A see ẹbun akara oyinbo lasan lee pa owe nla fun ẹda kan

Mercy Aigbe ni n se ni oun rẹrin iyangi, to si lọra lati se amin.

"Emi ko mọ pe Ọlọrun n lo ohun asiwere lati da Ọlọgbọn mi laamu ni, lati ẹnu Luminee si ni Ọlọrun ti fun mi ni ẹri ile tuntun."

Mercy ni lẹyin osu diẹ ti oun gba ẹbun akara oyinbo naa, ni oun ra ile tuntun fun ara oun ni adugbo to rẹwa ni ilu Eko,

"Ẹ dakun, ẹ ki iya onile tuntun" ni Mercy sọ, pẹlu afikun pe oun ti ri oore ọfẹ Ọlọrun, ti iyanu rẹ si ti wa oun ri. O ni ibẹrẹ oun ọtun ree ninu aye oun, Ogo si ni fun Ọlọrun.