Buhari: N kò dunnú sí àyípadà táwọn asòfin se sí ìsúná

Ààrẹ Buhari Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari buwọ́ lu ìsúná 2018

Ààrẹ buwọ́ lu ìwé ètò ìsúná Nàìjíríà lẹ́yìn osù kẹfà tí wọ́n se àgbéjáde rẹ̀ níwájú ilé ìgbìmọ̀ asòfin.

Lára ohun tí Ààrẹ mẹ́nu bà gẹ́gẹ́ bí àkùdé nínú ètò ìsúná ọ̀hún ni pípèsè fún àwọn isẹ àkànse ohun amáyérọrùn kọ̀ọ̀kan bíi ibùdó ìpèsè iná ti Mambilla, afára tó fi mọ́ òpópónà Niger, àwọn ọ̀nà apá Ílà Oòrùn-Ìwọ̀ Oòrùn, òpópónà Bonny sí Bodo, òpópónà Eko sí Ibadan tó fi mọ́ ojú ọ̀na irin Itakpe sí Ajaokuta.

Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ Buhari ní inú òhun kò dùn sí àwọn àyípadà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin se sí ìwé ètò ìsúná tí òun fi ṣọwọ́ sí wọn. Ó ní bó ṣe yẹ kó jẹ́ ni wí pé ẹ̀ka aláṣẹ ló yẹ kó dábàá ètò ìsúná, nítorí òun ló mọ̀ tó sì lè sàlàyé àwọn àlàkalẹ̀ àti iṣẹ́ àkànṣe.

Sùgbọ́n ó ní wọn kò kọbi ara sí èyí tó nínú ohun tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí òun. "Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin gé owó tó tó bílíọ̀nù N347 nínú N4,700 tó yẹ kó wà fún iṣẹ́ àkànṣe èyí tó fi ṣọwọ́ sí wọn fún àgbéyẹ̀wò, ó sì dábàá iṣẹ́ àkànṣe 6,403 tó tó bílíọ́nù N578.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Sáájú, báyìí ni ó se wà nínú àbá ètò ìsúná Nàìjíríà:

Pípín

Iye owó =N=9,120,334,988,225 ni ó wà nínú ìwé ètò ìsúná náà lára èyí tí =N=530,421368,624 ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún owó tí wọ́n gbudọ̀ fi ṣọwọ́ èyí tó di dandan.

=N=2,203,835,365,699 ló wà fún gbèsè sísan; =N=3,512,677,902,077 wà fún owónàá àtìgbàdégbà èyí tí kìí se gbèsè nígbàtí =N=2,873,400,351,825 jẹ́ owó fún ìdàgbàsókè àkànṣe iṣẹ́ ńlá ńlá.

Owó fún ìdàgbàsókè àkànṣe iṣẹ́ ńlá ńlá ọ̀hún fún ọdún yìí máa parí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kéjìlá ọdún 2018.

Ìlànà

(i) Wọn yóò kó iye owó tó wà nínú àlàkalẹ̀ pínpín lókè yìí fún àwọn adarí àkànse iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan bó ṣe wà lákọsílẹ̀ àbá ètò ìsúná.

(ii) Kò ní sí àgbéjádé iye owó kankan nínú èyí tó ń wọlé fún ìjọba lẹ́yìn ọdún tí wọ́n darukọ nínú àlàkalẹ̀ pínpín.

(iii) Fún èrèdí ohun tó wà fún gangan gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ [pínpín nìkan ni wọn yóò fi gbé àwọn owó kalẹ̀.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.