Ìjàmbá Ojúẹlẹ́gbá: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni irúfẹ́ àjálù bẹ́ẹ̀ ti wáyé

Ìjàmbá Ojúẹlẹ́gbá: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni irúfẹ́ àjálù bẹ́ẹ̀ ti wáyé

Oludarí kan ní àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko sọ fún BBC Yorùbá pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó ń fa ìjàmbá lórí afárá yìí ni ẹrù akójù táwọn ọ̀lọ́kọ̀ máa ń kó.

Eniyan mẹta, ninu eyi taa ti ri awakọ bọ́ọ́sì kan àti agbèrò ló padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ agbegi ni afara agbegbe Ojuẹlẹgba ni ipinlẹ Eko.

Isẹlẹ naa waye nigba ti igi nla rebọ lati ori ọkọ agbegi to n sọkalẹ lori afara agbegbe Ojuẹlẹgba ni ilu Eko, ti igi naa si wo lu awọn ọkọ tó ń rékọjá lórí afárá náà.

Ajọ to n risi ọro pajawiri ni ipinlẹ Eko, Lasema to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, fi kun un pe eniyan mẹta naa ku loju ẹsẹ, ti ọpọ si farapa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: