AFCON 2019: Nàìjírìa àti Uganda fi ijó bẹ́ẹ ni ìlú Asaba
Super eagles fi ijó bẹ́ẹ lẹ́yìn tí wọ́n ta òmì pẹ̀lú Uganda
Inu ẹni kii dun ka pa mọra.
Bẹẹ gẹgẹ lọrọ ri pẹlu ikọ Super Eagles ati Uganda lẹyin ti wọn gba ọọmi 0-0 ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ lọjọ Iṣẹgun nilu Asaba.
Fidio ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles fi lede lori opo Twitter wọn fihan bi ẹlẹsẹ ayo, Ahmed Musa, adilemun, Ikechukwu Ezenwa ati awọn agbabọọlu miran ti kijo mọlẹ.
Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Super Eagles
Ikọ Super Eagles n yọ muda
Koda akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria Gernot Rohr ati awọn igbakeji aarẹ ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria Shehu Dikko naa ko gbẹyin ninu ijo ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
AFCON 2019: Nàìjírìa àti Uganda ta òmì 0-0 ní ìlú Asaba
Ikọ Super Eagles ta omi 0-0 ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ ti wọn gba lọjọ Iṣẹgun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Uganda.
Ni papa iṣere Stephen Keshi nilu Asaba ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye lẹyin ọjọ mẹta ti wọn pegede lati kopa ninu idije ere bọọlu ilẹ Afirika AFCON 2019 ti yoo waye lorilẹede Cameroon.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Super Eagles ti pegede fun AFCON 2019
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria Gernot Rohr lo awọn agbaọjẹ agbabọọlu bi Alex Iwobi, Ahmed Musa, Oghenekaro Etebo ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ṣugbọn bi wọn ti gbiyanju to, wọn kuna lati gbayo sawọn nile Uganda.
Uganda naa ti pegede lati kopa ninu idije AFCON 2019 lẹyin ti wọn fiya jẹ Cape Verde pẹlu ami ayo kan sodo.
Super Eagles yege láti kópa nínú ìdíje AFCON 2019
Agbábọ̀ọ̀lù nígbàkan rí fun Super Eagles,Mutiu Adepoju ti gba ikọ Super Eagles niyanju lati bẹrẹ imura ni perewu lẹyin ti wọn pegede fun AFCON 2019.
Adepoju fi ọrọ iyanju yi lede nigba ti o n ba ikọ BBC Yoruba sọrọ ni kete ti ifẹsẹwọnsẹ laarin Naijiria ati South Africa wa si opin lọjọ abamẹta.
Agbabọọlu agba ọjẹ Mutiu Adepoju ni aaya bẹ silẹ o bẹ́ sare lọrọ to de ilẹ
O ni ohun idunnu ni pe Super Eagles yoo kopa ni idije naa lẹyin ọdun maarun ti wọn kopa kẹyin sugbọn wọn ni lati san bantẹ wọn daada nitori pe ibẹrẹ ko ni oniṣẹ.
Mutiu Adepoju ni ki akọnimọọgba wọn yi ma lo awọn to kopa titi ti wọn fi pegede ṣugbọn ti o ba di dandan wọn le mu atunto ba awọn aye kan ti o ba di dandan
Ni bayi awọn ikọSuper Eagles ti n fi ijo ati ayo dupe fun aseyọri yi ninu fọnran fidio ti wọn fi sita loju opo Twitter wọn.
Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria pegede, wọn si fi gbọọrọ jẹka lati kopa ninu idije AFCON 2019.
Ọmi ayo kọọkan ti wọn gba pẹlu South Africa lo mu wọn ṣe aṣeyọri yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
'Oun tí Kunle Afolayan ṣe sí mi, mi ò lè ṣeé sí i'
Loju opo Twitter Super Eagles, gbagada ni wọn gbe ikede ikini ku orire aseyori yi sibẹ.
Eyi ni igba akọkọ ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjírìa yoo kopa ninu AFCON lati 2013 ti wọn ti kopa kẹyin.
Ni bayi, Naijiria ti ni ami ayo mẹwa, ti South Africa to ṣe ipo keji si ni ami ayo mẹsan.
Awọn mejeeji ti pegede lati kopa ninu idije AFCON lati isọri kaarun.
Oríṣun àwòrán, ng_supereagles/Instagram
Ikọ̀ Super Eagles pegedé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Libya
Saaju ni ẹlẹsẹ ayo fun ikọ Super Eagles, Ahmed Musa, ti fọwọ sọya pe Naijiria yoo na South Africa mọle ninu ifẹsẹwọnsẹ komẹsẹoyọ AFCON 2019 lọjọ Abamẹta.
Ikọ Super Eagles balẹ si ilu Johannesburg laarọ kutu ọjọ Ẹti lati ilu Asaba nipinlẹ Delta.
Ni papa iṣere Stephen Keshi to wa nilu Asaba ni ikọ naa ti ṣe igbaradi fun ọjọ mẹrin gbako ṣaaju ere bọọlu ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
'Mo máa ń fi orin ìbílẹ̀ tiwa n tiwa gbá ti òkè òkun lẹ́gbẹ̀ẹ́'
Ìgbé ayé Instagram fún ọ́sẹ̀ kan
Musa ni gbogbo agbabọọlu ikọ Super Eagles lo ti wa ni igbaradi fun Bafana Bafana, bẹẹ ni awọn yoo si rẹrin ni ipari ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ẹwẹ, South Africa na Naijiria mọle ninu ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ yii, eleyi lo jẹ ki ẹlẹsẹ ayo Musa sọ pe awọn ṣetan lati gbẹsan.
Agogo mẹta ọsan lọjọ Abamẹta ni ere bọọlu ọhun yoobẹrẹ ni papa iṣere FNB nilu Johannesburg.
Rohr gb'óṣùbà káré fún Super Eagles
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria Gernot Rohr ti gb'oṣuba kare fun ikọ̀ Super Eagles lẹyin ti jáwẹ olúborí ninu ifẹsẹwọnṣe wọn pẹlu Libya lọjọ Iṣẹgun.
Oríṣun àwòrán, ng_supereagles/Instagram
Ikọ̀ Super Eagles ti saaju pegedé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Libya
Ami ayo mẹta si méjì ni Naijiria fi fagba han Libya ninu ere bọọlu ti wọn yoo fi pegede fun idije ilẹ Afirika AFCON 2019.
Ẹlẹsẹ-ayo Odion Ighalo lo kọkọ gba ayo wọle fun Naijiria ki Ahmed Musa to sọ ọ di meji fun ikọ Super Eagles.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Libya gbiyanju lati gba ayo meji wọle, ṣugbọn Igbalo tún gba ayo kan wọle si lati ri i pe Naijiria jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Oríṣun àwòrán, Ighalojude/Instagram
Odion Ighalo tún fakọyọ fún Nàìjírìa
Naijiria lo n siwaju bayi ni isọri karun un fun idije ilẹ Afirika lọdun to n bọ lorilẹede Cameroon, AFCON 2019.
Ahmed Musa fakọyọ ni Idije Ife Ẹyẹ Agbaye Russia 2018
Ahmed Musa dábírà ní apá keji ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà bí ó ṣe sọ àmi ayò méjèèjì tí Naijiria fi bori wọlé.
Ṣe ni agbabọọlù Iceland Gylfi Þór Sigurðsson tí kò bá tún fún wọn ní ayò kan pẹlu wòmí-n-gba-sí-ọ, gbáa sígbó.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ahmed Musa dábírà ní apá keji ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà
Ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ló jẹ́ kó ṣeéṣe fún Naijiria láti tẹ̀síwájú nínú idíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ní Russia.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
World Cup 2018: Àwọn ọmọ Nàíjíríà kún fáyọ̀ lóri Super Eagles
Bí ayò náà ṣe parí ni Twitter gbiná pẹ̀lú ìdùnú tí àwọn ọmọ Naijiria nilé àti lókèère fi ays wọn hàn.
Aarẹ Muhammadu Buhari ní inú òun dún gan ni.
Igbákejì Aarẹ Naijiria, Ọjọ̀gbọn Yemi Osinbajo ko gbẹ́yìn.
Àwọn ọmọ Naijiria ni ayọ̀ wọn kò lópin.