APC Convention: Àwọn èèkàn ẹgbẹ́ kò gbẹ́yìn níbẹ̀

Ààrẹ Muhammadu Buhari àti igbákejì rẹ̀ ọjọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo balẹ̀ sí gbọ̀gàn Eagle Square fún ìpàdé Ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC) .

Image copyright APC/tritter
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari àti igabkeji rẹ̀ níbi ìpade ẹgbk òṣelú APC

Aarẹ ile asofin apapọ, Bukọla Saraki naa ko gbẹyin nibi ipade apapọ ẹgbẹ oselu APC.

Oni nkan laa jẹ ko see. Alaga apapọ tuntun fẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomọlẹ ati Iyawo rẹ, Lara, ree nibi ipade apapọ APC, to ti wọle bii alaga tuntun.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatai Hammed naa wa lara awọn eekan ilu to yọju sibi ipade apapọ APC naa.

Image copyright APC/twitter
Àkọlé àwòrán Gonina ìpínlẹ̀ Kwara Abdulfatah Ahmed lásìkò ìforúkaọsílẹ̀

Ankara yẹbẹ-yẹbẹ ni, nibi ti awọn asoju ipinlẹ Abia joko si.

Àwọn asoju lati ipinlẹ Jigawa se bẹbẹ, koda wọn duro re o

Àwọn asoju lati ipinlẹ Kano gan se bẹbẹ lọhun.

Awọn asoju lati ipinlẹ Ọsun ree o, oju wọn gun rege, ankara wọn to jẹ asọ ẹgbẹjọda gan fa ni mọra.

Awọn eeyan wa lati ipinlẹ Ondo naa ni awọn wa o, Gomina Rotimi Akeredolu ree, to nki awọn eeyan.

N se ni asia ami idamọ̀ ẹgbẹ oselu APC n fẹ lẹlẹ lasiko ipade apapọ ẹgbẹ oselu naa.

Hajia Salamatu to ń dupò olorí obinrin fún ẹgbẹ́ ti yẹ̀ba fun akẹgbẹ́ rẹ̀, Ramatu Tijani Aliyu, bákan náà ló jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

Image copyright APc twitter
Àkọlé àwòrán Awọn asojú ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan níbi ìpàde APC

Gbogbo àwọn èèkan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló péju níbi ìpàdé ìdìbò yan olóyè ẹgbẹ́ tuntun, to fi mọ Bọla Tinubu ati Yakubu Dogara.

Image copyright APC/ twitter
Àkọlé àwòrán Gbogbo àwọn èèkan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló péju níbi ìpàdé ìdìbò yan olóyè ẹgbẹ́ tuntun

Ẹsẹ ko gbero ni ilu Abuja nitori iupade apapọ ẹgbẹ oselu APC.

Image copyright APC/twitter
Àkọlé àwòrán Ohun gbogbo ló ń lọ létòletò níbi ètò ìdìbò tó ń lọ L'abuja