APC: Gbogbo ìpínẹ̀ lẹ́tọ lati yan àsoju lọ́nà to wù wọn

Oshiomole ati Buhari Image copyright APC/twitter
Àkọlé àwòrán APC: Gbogbo ìpínẹ̀ lẹ́tọ lati yan àsoju lọ́nà to wù wọn

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) nínú àbájáde ìpàdé tó wáyé lónìí tí ni àwọn o ní fá ori apá kan dá pakan sí láti yan àsọju ẹgbẹ́ òṣèlú náà fún ààrẹ níbi ìdìbò gbogboogbo ọdun 2019.

Nínú ìpàdé àpérò ti wọn ṣe lọ́nìí ni wọn ti sàlàyé pé gbogbo ọmọ ẹgbk ni yóò ní ànfàní láti yan ẹni tó bá wù wọn pẹ̀lú ìdìbò ti yóò fààyè gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ́, nígbà ti àwọn ìpínlẹ̀ yóò yan ọ̀nà tó ba wù wọn láti yan ẹni ti wọn ń fẹ́

Image copyright APC/twitter
Àkọlé àwòrán APC: Gbogbo ìpínẹ̀ lẹ́tọ lati yan àsoju lọ́nà to wù wọn

Wọn fi kún-ún pé ]ipínlẹ̀ to bá pinu lati tọ ìlana ti ile ẹgbẹ ti gbogboogbo lò yóò nílati kọ̀wé ráńṣẹ́ àkọwé ẹgbk àpapọ̀.

APC Convention: Adams Oshiomole, di alága àpapọ̀ láì látakò

Image copyright APc/twitter
Àkọlé àwòrán Adam Oshiolmolẹ̀ ló jáwé olúborí

Ẹgbẹ oṣelu APC ti kede Adams Aliyu Oshiomole gẹgẹ bii alaga tuntun fun ẹgbẹ oṣelu naa.

Níbi ìpàdé ìdìbò ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń lọ lọ́wọ́ nílu Abuja ni wọn ti kede Adams Aliyu Oshiomole gẹgẹ bii alaga tuntun fun ẹgbẹ oṣelu ọhun.

Oshiomole, ti o ti figba kan ri jẹ aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati gomina ipinlẹ Edo fun ọdun mẹjọ, lo n bọ si ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ti gbogbo awọn to kọkọ ti fi ifẹ han lati dije fun ipo naa ju awa silẹ pe, awọn ko ṣe mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ oṣelu APC kede alaga apapọ wọn, lẹyin ti wọn ti ṣe idibo 'ẹ gbohun soke fun ẹni ti ẹ fẹ' laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa.

Ipo mejidinlogun miran ti ko si alatako fun, ni wọn tun kede lọjọ abamẹta.

Image copyright APc/twitter
Àkọlé àwòrán Adam Oshiolmolẹ̀ ló jáwé olúborí

Kọlawọle Oluwajana, lati ìpínlẹ̀ Ondo, ni alaga fun ẹkun iwọ-oorun guusu orilẹede yii ninu ẹgbẹ oselu APC.

Ẹkùn ààrin gbùn-gbùn Gúúsù l‘ẹgbẹ́ APC fi ipò alága sí

Lara awọn to kọkọ fi ifẹ han si ati dije ipo naa, lo gbégbá olokè nitori kò sé sí olùdíje míìràn tó ń báa dupo,

Ọjọgbọn Osunbor ati alaga to n fipo silẹ John Oyegun, sì ni wọn ti fi ìfẹ́ hàn sááju sí ipò nàá àmọ́ wọn yẹ́bá lẹ́yìn-ò-rẹyìn.

Tí ẹ ò bá gbàgbé, APC tí pín ipò alága ẹgbẹ́ fẹ́kùn ààrin gbùn-gbùn Gúúsù orílẹ̀èdè yìí, tí Oshiomolè sì dìde láì ni alátakò