Zimbabwe àti Ethopia: Adó olóró méjì ní gbàngàn ìpolongo

Emmerson Mnangagwa
Àkọlé àwòrán Ààrẹ orílẹ̀-èdè Zimbabwe ní bi ìpolongo ìbò

Ori lo ko Ààrẹ orilẹ́-èdè Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa yọ lónìí lọ́wọ́ àdó olóró tó bú ní gbàngàn ìpolongo ìdìbò ẹgbẹ́ oṣelu Zanu PF sájúu ìdìbò gbogbogbò tí yóò wáyé ní òpin osù yìí.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún tó wáyé ní pápá ìṣeré white city ní ilú Bulawayo jọ bí ẹni pé wọn dojú rẹ̀ kọ ààrẹ gan ni sugbọn ori kò padà lẹ́yìn rẹ̀, nítorí kété tí Mnangagwa bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ tan ni àdó olóró náà dáhùn.

Bi ó tilẹ jẹ́ pé ààrẹ kò farapa rárá gẹ́gẹ́ bí ile iṣẹ́ móhùmáwòran orilẹede náà ṣe sọ, sùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fún àgbákejì ààrẹ Kembo Mohadi àtí ìyàwó igbákejì ààrẹ àkọ́kọ́ Constantino Chiwenga bí o ṣe fí ara pa yánayàna

Mnangagwa gorí oyè nínú oṣù kọkànlá ọdún to kọja lẹ́yìn tí wọ́n lé Robert Mugabe kúrò ní ìjọba.

Ẹ̀wẹ̀, lórilẹ̀-èdè Ethopia bákan náà, atúlúto tuntun tó jẹ́ olóòtú ìjọba Abiy Ahmed ku díẹ̀ kó fara káásá níbi adó olóró tú dún níbí ìwóde tó wáyé ní Meskel Square nílu Addis Ababa tí ènìyàn kan pàdánù ẹ̀mi rẹ̀ súgbọ́n tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ farapa tí o fí mọ́ àwọm mẹ́wàá kan ti wọn ò jẹ́ ará ayé tí wọn ò sì jẹ́ èrò ọ̀run.

Image copyright Fitsum Arega/twitter
Àkọlé àwòrán Awọn olólùfẹ́ olóòtú ìjọba Abiy Ahmed lásìkò tí tó ń báwọn sọ̀rọ̀

Kété ti Abiy parí ọ̀rọ̀ ìṣítí rẹ̀ níbi ti ogúnlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn tí péjọ sí ní wọn ju àdó olóró náà sí apá ibití èrò pọ̀ sí lórí ìtàgé ní wọn sáré gbe olóòtú ìjọba sá lọ.

Lẹ̀yìn iṣẹ̀lẹ̀ òhún ní olóòtú ìjọba Abiy sọ̀rọ̀ lórí móhùnmáwòrán pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló kú, sùgbọ́n lẹ́yìn náà ní mínísítà fún ètò ìlera ní ènìyàn kan péré ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rin, ènìyàn métàlééládọ́ọ́jọ ló farapa tí ènìyàn mẹ́wàá sì wà ní ipò tó bani lẹ́rù.