PDP: kò sí àpẹẹrẹ ìṣèjọba àwa-ara-wa ninu ìdìbo APC

Image copyright APC/twitter
Àkọlé àwòrán Àwọn ọ̀dọ́ APC rọọ́ lati máa fárí apákan dá apá kan síAdams Oshiomole

Ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Peolpe (PDP) ní ìbànújẹ́ ló jẹ́ láti rí bí àwọn olùkópa dupò níbi ìpádé APC se ń jáde pé àwọn juwọ́ sílẹ̀ fún elòmíran.

PDP sọ èyí dí mímọ̀ lọ́rí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter rẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò fààyè gbá ìjọba àwa-ara-wa.

Kíní àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ lóri ọ̀rọ̀ tí PDP sọ yìí lórí twitter

Wọn ní ohun tó ṣelẹ̀ sàfihan bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣ ń gbé nínú ibẹ̀rù bojo.

Ẹ̀wẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ oṣèlú All Progressives Congress (APC) tí kí alága tuntun fún ẹgbẹ́ Adams Aliyu Oshiomole kú oríre ìyàn sípò rẹ̀.

Àwọn ọ̀dọ́ APC ọ̀hún sọ ọ̀rọ̀ náà dí mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ akowe rẹ̀ Collins Edwin, pé o se pàtàkì láti ríi dájú pé kò fí ara rẹ̀ ji fún àwọn ẹgbẹ́ alátakò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAPC Convention: Àwọn aṣojú láti Warri yọ igi sí ara wọn

Gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ ìpèníjà ọjọ́ iwájú kò ní onka nítorí náà kí alága kó gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ mọ́ra fún ànàfáni ìdìbò gbogboogbò tó ń bọ̀ lọ́dun 2019.