Ìpàdé àpapọ̀ APC: 5000 ọlọ́pàà wà níkàlẹ̀ fún ààbò

Ẹgbẹrun marun ọlọpaa ni yoo mojuto eto abo nibi ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu APC ti o n waye lọjọ abamẹta nilu Abuja.

Bakanna ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa tun ṣalaye pe baluu kekeeke meji pẹlu ọkọ ayẹta mẹfa lo wa nikalẹ lati da awọn to ba fẹ dómi alaafia ru nibẹ lọwọ kọ.

Image copyright #APCNationalConvention
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ oṣelu APC n yan awọn adari rẹ fun ọdun mẹrin miran

Awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe PMF, ikọ agbogun ti iwa igbesunmọmi, CTU atawọn ikọ akọṣẹmọṣẹ nipa ado oloro, EOD ati bẹẹbẹ lọ.

Ni bayii, ẹgbẹ oṣelu PDP ti fi ẹsun kan APC pe owo ilu ti wọn ji ko ni wọn fi ṣeto ipade awọn wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan salaye ninu atẹjade kan pe ipolongo iwa aiṣootọ ati iwa ijẹkujẹ ni APC n fi ipade apapọ wọn ṣe.